Ile-ẹjọ to ga ju lọ fontẹ lu Ọbasẹki bii gomina Edo, wọn ni ki ẹgbẹ APC sanwo itanran

Faith Adebọla

Gbogbo akitiyan ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) lati yi abajade ibo sipo gomina to waye nipinlẹ Edo lọdun to kọja, ninu eyi ti wọn ti kede Godwin Nogheghase Obaseki ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori, ti ja si pabo pẹlu bi ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ ṣe fontẹ lu u pe ọkunrin naa lawọn araalu dibo yan loootọ, awọn o si ri abuku kan ninu iwe-ẹri rẹ.

Ilu Abuja ni wọn ti gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, awọn adajọ maraarun ti wọn wa lori aga idajọ ni wọn panu-pọ kede pe ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ ni ẹjọ ti APC ati aṣaaju ẹgbẹ ọhun kan, Oloye Edobor Williams, pe ta ko gomina naa, ti wọn ni iwe-ẹri ti Ọbaseki n ko kiri ko mọyan lori.

Ile-ẹjọ ni awọn olupẹjọ ko fi ẹri kankan gbe ẹsun wọn lẹsẹ, awawi ati agbọsọ ni ohun ti wọn ro lẹjọ.

Wọn ni ko si eyikeyii ninu awọn ileewe girama ati Fasiti ti olujẹjọ naa sọ pe oun lọ to jade waa jẹrii pe irọ lo pa, kaka bẹẹ, ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ fihan pe ko si ayederu kankan ninu awọn sabukeeti rẹ.

Latari eyi, wọn ni awọn fara mọ awọn idajọ ile-ẹjọ giga ti ọjọ kẹsan-an, oṣu ki-in-ni, ọdun yii, ati ti ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta, ọdun yii, ninu eyi tawọn kootu mejeeji ti kọkọ da ẹjọ naa nu bii omi iṣanwọ tẹlẹ.

Wọn ni gomina Ọbaseki peregede, o wẹ, o yan kain-kain, oun si lo jawe olubori. Wọn ni ki ẹgbẹ APC lọọ san owo itanran miliọnu kan naira fun olujẹjọ naa, bẹẹ ni ki olupẹjọ keji sanwo pẹlu.

Pẹlu idajọ yii, awuyewuye lori eto idibo to gbe Gomina Obaseki wọle yoo lọ sodo lọọ mu’mi wayi.

Leave a Reply