Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọrọ oṣelu to n lọ lọwọ nipinlẹ Ondo gbọna mi-in yọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pẹlu bi awọn ọdọ kan ṣe fẹhonu han lori ọrọ ọmọkunrin kan ti wọn pa lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Ọmọkunrun ti wọn porukọ rẹ ni Taye yii lawọn tọọgi kan ti wọn ni wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ APC ṣe akọlu si ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ naa latari bo ṣe kuro ninu ẹgbẹ wọn, to si lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ZLP.
ALAROYE gbọ pe ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ APC ni wọn pe oloogbe ọhun tẹlẹ ko too kuro, to si lọọ darapọ mọ ẹgbẹ PDP.
Laipẹ yii lo tun sa kuro ninu ẹgbẹ PDP, to si ba ẹgbẹ ZLP lọ.
Fila ẹgbẹ tuntun to lọọ darapọ mọ yii to de sori lalẹ ọjọ iṣẹlẹ naa ni wọn lo bi awọn tọọgi APC ninu tí wọn fi kọlu u lagbegbe Sabo, niluu Alade-Idanre.
Loootọ lo kọkọ ja fitafita, to si gbiyanju lati sa mọ wọn lọwọ, ṣugbọn ti ko ti i raaye sa jinna tọwọ awọn to n le e fi pada tẹ ẹ, ti wọn si ṣa a pa mọ inu igbo to sa wọ.
Eyi naa lo ṣokunfa bawọn ọdọ kan ṣe binu fọn sì igboro ilu naa laaarọ kutukutu Ọjọbọ, Tọsidee, pẹlu aake, ada, atawọn nnkan ija mi-in lati fẹhonu han ta ko iku oloogbe ọhun.
Ṣe ni wọn sun taya ọkọ si gbogbo oju ọna abawọlu Alade, ti wọn si n fa awọn posita oludije ẹgbẹ APC ti wọn ba ti rí ya.