‘Nitori owo ni mo ṣe bẹ ọrẹ mi lori o!’, Moses lo sọ bẹẹ

Afi ki eeyan maa ṣọra ko too finu han fẹni kan. Awọn ọrẹ a maa ṣeku pa ara wọn o. Bo ba ṣe pe Abuchi ko fi foonu rẹ han ọrẹ rẹ, Moses, to si sọ fun un pe ẹgbọn oun lo fowo ile ti oun n ba a kọ niluu awọn ranṣẹ soun lati South Afrika, o ṣee ṣe kọmọọkunrin naa ṣi wa laye o. Ṣugbọn Abuchi sọ fun Moses, o si fi alaati ori foonu rẹ han an, ni Moses ba foju ba nmiliọnu mẹtala, n lo ba fọgbọn tan Abuchi, o si gun un pa ko too bẹ ẹ lori, o si ti nawo naa jinna aki ọwọ awọn ọlọpaa too to o.

Bi ọrọ ṣe ṣẹlẹ ni pe ileeṣẹ omi kan ni ilu Auchi ni Moses Moses ti n ṣiṣẹ, o ti kawe jade ni poli, nigba ti ko ri iṣẹ mi-i ṣe lo fi n ba wọn ṣiṣẹ nileeṣe piọ-wọta yii. NIbẹ ni Abuchi ti ba  a, oun lo si kọ Abuchi ni bi yoo ti maa lo maṣinni omi naa. Ohun to sọ wọn di korikosun ree. Lọjo kan ni Abuchi sọ fun ọrẹ rẹ pe bọọda oun ti oun n ba kọle siluu awon ṣẹṣẹ fowo ranṣẹ soun ni o, o si fii alaati ori foonu rẹ han an pe ko wo o, miliọnu mẹtala Naira ni.

Lẹsẹkẹsẹ ni ero aburu wọ inu Moses, ṣugbọn Abuchi ko mọ nnkan kan. Moses fi ọgbọn tan Abuchi ni ọjọ keji, o si mọ nọmba to n lo lati fi ṣi foonu rẹ, ninu foonu yii naa lo si ti ri nọmba to n lo lati fi gba owo lori kaadi ee-ti-ẹẹmu (ATM) rẹ naa.

Nigba ti eleyii ti pe, o tan Abuchi  pe ko waa ba oun ṣiṣẹ alẹ lọjọ kan, bi wọn si ti n ṣiṣẹ lọ lo fọgbọn tan an sita, n lo ba gun un lọbẹ latẹyin lẹẹkan naa, ni Abuchi ba ku. Lẹyin to ku, Moses bẹ ẹ lori ki ẹnikẹni ma baa da oku ẹ mọ, o si gbe e lọ sinu igbo nitosi ibi iṣe wọn. N lo ba yọ foonu ati kaadi ATM rẹ.

Kia lo ti wa awọn ọrẹ kan ti wọn mọ nipa bi wọn ti n ṣi foonu ati ATM, awọn ni wọn si ran an lọwọ to fi bẹrẹ si i fi kinni naa gbowo.  O ti gbọwo fun bii oṣu meloo kan, ti awọn araale si ti daamu daamu ti wọn ko ri Abuchi, ki ẹni to fi owo ranṣe si i lati South Africa too kọwe si ọga ọlọpaa pata, niyẹn ba paṣẹ ki wọn wadii ẹ.

Banki ti Abuchi n lo ni wọn lọ lati lọọ wo o boya wọn n lo ATM ẹ, nigba ti wọn si ti ri i pe wọn n gbowo nibẹ lẹyin to ti ku tan, wọn bẹre si i ṣa awọn ti wọn ni POS to fi n gbowo naa kaakri, nibẹ ni wọn si ti mu Moses Moses.

O kuku jẹwọ. O ni nigba toun jade ti oun ko riṣẹ loun n lọọ ṣiṣẹ ni ileeṣẹ omi, nigba ti oun si ri ọrẹ oun pẹlu iru owo nla bẹẹ, ti oun ko ri iru ẹ ri, oun ro pe anfaani ni eleyii jẹ foun naa lati ni owo toun. Ọwọ ti tẹ oun atawọn ọrẹ rẹ, wọn yoo si fimu danrin!

 

 

Leave a Reply