Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Oṣemawe tilu Ondo, Ọba Victor Kiladejọ, ti ibinu lori bi ọwọngogo ọja ṣe n tẹsiwaju, leyii to si n fara ni ọpọ awọn olugbe ilu ọhun.
ALAROYE gbọ pe Ọba Kiladejọ ti kọkọ pepade pajawiri pẹlu awọn oloye ati iyalọja ilu, Abilekọ Bukọla Akinniyi, ti wọn si jọ ṣagbeyẹwo bi awọn nnkan ṣe wọn gogo niluu, ati ohun to le ṣokunfa rẹ.
Ninu ipade ọhun ni Oṣemawe ti fun awọn ọlọja lọjọ meje kí wọn fi lọọ gbe igbesẹ lori bi awọn ọja to wọn gogo yoo ṣe walẹ kiakia. Aisi iyatọ rara lẹyin ti gbedeke naa pari lo mu ki Kabiyesi atawọn ọmọ igbimọ rẹ pinnu ati fi ofin ati ilana tawọn ọlọja ilu gbọdọ tẹle lelẹ fun wọn.
Eyi lawọn ofin ti wọn fi de gbogbo ọlọja to ba ṣi nifẹẹ lati maa ṣowo kara-kata niluu Ondo.
Ko gbọdọ sọrọ pe wọn n fipa mu ẹnikẹni lati wọnu ẹgbẹ kan tabi omiiran, ẹnikẹni lo lanfaani ati maa ta ọja rẹ bo ṣe wu u tabi niye to ba wu u. Wọn ni aaye tun wa fun gbogbo ẹni to ba fẹẹ waa ṣowo tabi ta ọja niluu Ondo ati agbegbe rẹ lati awọn ilu miiran lati waa ṣe bẹẹ lai si ibẹru pe ẹgbẹ kan yoo mu awọn.
Wọn ni awọn ontaja wọnyi le pe iyalọja atawọn ijoye ilu sori aago wọn loju-ẹsẹ lati fẹjọ ẹnikẹni to ba fẹẹ di wọn lọwọ owo ṣiṣe sun, bakan naa ni wọn paṣẹ fun iyalọja lati ṣeto b’awọn eeyan yoo ṣe gbọ nipa ofin tuntun naa.
Gbogbo awọn ọja bii, Odosida, Okelisa, Ayeyẹmi, Akinjagunla, Igba, Ọka, Odojọmu atawọn ọja mi-in ti wọn ti pa ni wọn gbọdọ di sisi pada lẹyẹ-o-ṣọka, ati pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lati da ọja Ṣáṣá ati Kára silẹ kun awọn ọja wọnyi.
Igbimọ Oṣemawe tilu Ondo ni asẹ ti jade lati asiko yii lọ pe ki gbogbo awọn ile-epo ti wọn ba ti n gbowo le epo wọn pupọ ju, tabi ti wọn ba n gbe epo pamọ lai ta a fawọn araalu di titi pa loju-ẹsẹ.
Aṣa yiyọ afikun owo lori ọja ti wọn ba sanwo rẹ pẹlu POS ni wọn lo gbọdọ dopin, bẹẹ lawọn tọọgi tabi awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ko gbọdọ tun yọ awọn awakọ to ba n ko ọja wọlu lẹnu mọ, wọn lẹni to ba dan iru rẹ wo yoo ri ibinu ilu.
Wọn rọ awọn to rọwọ mu laarin ilu lati ro awọn ọdọ lagbara pẹlu iṣẹ agbẹ ati okoowo ṣiṣe, ki adinku le tete ba iṣoro iyan ati ebi to n b’awọn eeyan finra lọwọ.
Igbimọ Oṣemawe ni awọn ti ṣeto awọn ọlọpaa inu kan ti yoo maa kaakiri lati rí i daju pe awọn ọlọja tẹle gbogbo ilana tuntun ti ilu ṣẹṣẹ fi lelẹ naa.