Nitori Sunday Igboho, Akeugbagold ko awọn aafaa jọ lati gbadura fun un n’Ibadan

Jọke Amọri

Ba a ṣe n sọ yii, ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ti wọle adura bayii, ti wọn si n gbadura kikan kikan pe ki Ọlọrun gba akoso, ko si ko Sunday Igboho jade ninu wahala ti ijọba Naijiria ko o si.

Bi awọn oniṣẹṣe ṣe n gba tiwọn, bẹẹ lawọn Onigbagbọ ati Musulumi naa n gbadura.

Lara awọn ti ko mu ọrọ naa ni kekere ni aafaa kan to fi ilu Ibadan ṣe ibugbe ti wọn n pe ni Sheik Akeugbagold Taofeeq.

Ninu fidio kan ti ALAROYE ri lori ẹrọ ayelujara lo ṣafihan aafaa naa to ti ko awọn aafaa ẹgbẹ rẹ jọ, ti wọn si n gbadura kikan kikan pe ki Ọlọrun mu Sunday pada wale layọ ati alaafia.

Ninu waasi rẹ lo ti sọ pe ki i ṣe aṣiṣe pe orileede Benin ni wọn ti mu Igboho. O ni eyi tọpẹ, nitori aarin awọn ọmọ iya rẹ to jẹ Yoruba lo wa.

Bakan naa ni Akeugbagold sọ pe adura ti awọn n gba lati oru, ti awọn si nigbagbọ pe Ọlọrun ti gbọ ni pe ki wọn ma ṣe da Sunday Igboho pada si Naijiria, dipo bẹẹ, ki adajọ fun un lanfaani lati maa lọ si orileede Germany to ni lọkan lati lọ. Bi eyi ko ba si ṣee ṣe, ki wọn fun un ni anfaani lati duro si ilẹ Benin. Eyi ko si mu iyọnu dani, nitori aarin awọn ọmọ iya rẹ lo wa.

Aafaa yi ni, ‘Iwọ Ọlọrun, a ko lewe, a ko ni oogun, iwọn Ọlọrun la gbẹkẹle, a si nigbagbọ pe oju ko ni i ti wa.

Ki i ṣe Akeugbagold nikan lo n gbadura yii. Ọpọlọpọ awọn oniṣẹṣe, awọn Onigbagbọ atawọn eeyan loriṣiriṣii ni wọn wọle adura pe ki Ọlọrun fa Igboho yọ lọwọ ọfin ijọba Naijiria.

Leave a Reply