Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni Olusẹgun Olushọla aka (Sholyment), to maa n ta ko ijọba lori ayelujara wọ Gomina Abdulrahman Abdulrasaq, Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Kwara, agbẹjọro agba to tun jẹ kọmiṣanna lẹka eto idajọ nipinlẹ Kwara ati Anti gomina, Khairat, lọ sile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara, fẹsun pe wọn fi i sahaamọ lọna aitọ, o si n beere fun ki wọn tu oun silẹ kiakia, ki wọn n tọrọ aforiji lọwọ oun ni gbangba. Bakan naa lo tun ni ki wọn san igba miliọnu naira owo gba ma binu fun oun.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, fiwe pe Oluṣẹgun Olushola, aka ( Sholyment.) to jẹ ọkan gboogi ninu ẹgbẹ oṣelu alatako PDP, nipinlẹ Kwara, ti wọn si fi i sahaamọ fẹsun pe o n sọrọ abuku si ijọba ipinlẹ Kwara, ti ẹgbẹ oṣelu PDP, si tutọ soke foju gba a, wọn naka aleebu si Gomina Abdulrahman Abdulrasaq pe o fi Olushọla si ahamọ lọna ti ko bofin mu.
Ni bayii Olushọla ti wọ gbogbo awọn tọrọ kan lọ si ile-ẹjọ pe ki wọn tu oun silẹ lahaamọ ati pe lẹyin itusilẹ ọhun, wọn o gbọdọ mu oun mọ. Bakan naa lo ni ki wọn san owo gba ma binu ti ko din ni igba miliọnu kan naira, ki wọn si tọrọ aforiji ni gbangba.