Nitori ti wọn lo ayederu iwe-ẹri, awọn alaṣẹ Kwara Poly le akẹkọọ mẹfa danu 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn alaṣẹ ile-ẹkọ Gbogbonise tipinlẹ Kwara, (Kwara State Polytechnic), ti le awọn ọmọ akẹkọọ HND mẹfa danu nileewe ọhun. Ẹsun pe ayederu iwe-ẹri Diploma ti wọn ko kalẹ fun awọn alaṣẹ ileewe ọhun.

Ninu atẹjade kan ti awọn alaṣẹ ileewe ọhun fi sita latọwọ Akọwe wọn, Ọgbẹni Ismail Onikoko Saliu, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, niluu Ilọrin, lo ti sọ pe awọn akẹkọọ tọrọ kan ni wọn lọọ ṣe ayederu iwe ẹri ND, ti aṣiri wọn si pada tu.

O tẹsiwaju pe lẹyin ti awọn akẹkọọ naa ti bura lọjọ ayẹyẹ igbani-wọle si ile ẹkọ naa pe wọn aa jẹ oloootọ, ṣugbọn to jẹ pe ayederu iwe-ẹri ni wọn n gbe kiri, ki wọn maa lọ sile wọn lai fi akoko ṣofo, ki wọn si ko gbogbo dukia ileewe naa to wa lọwọ wọn kalẹ ni ẹka onikaluku wọn, ko too di pe wọn o fi inu ọgba ile ẹkọ naa silẹ.

Gẹgẹ bii iroyin to tẹ wa lọwọ, awọn akẹkọọ tọrọ kan ni Greg Jessey Osariemhen, pẹlu Nọmba Matric rẹ (HND19ETMFT137); Quadir Toheeb Olamilekan, (HND19BAMFT600); Eyeowa Tomiwa Oluwakemi, (HND19PADFT592); Yusuf Zainab Abake, (HND19PADFT592); Lawal Abdulrahman, (HND19BFNFT380); Adeyẹye Ademọla Blessing,(HND19BFNFT555). Wọn ti waa rọ awọn akẹkọọ tọrọ kan ọhun pe ki wọn tẹle aṣẹ ti awọn alaṣẹ naa pa ki wọn si fi ọgba ileewe naa silẹ ni kiakia.

Leave a Reply