Nitori ti wọn n gbe ohun ija oloro kiri lọna aitọ, NSCDC mu afurasi meji ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn afurasi agbebọn meji Abdullahi Alaaji, ẹni ọdun mọkandinlogun ati John Ihenka, ẹni ọdun mọkandinlogoji, ni wọn ti wa ni ahamọ ajọ NSCDC, ni Kwara, fẹsun pe wọn n gbe ohun ija oloro kiri lọna aitọ.
Alukoro ẹsọ alaabo sifu difẹnsi, nipinlẹ Kwara, Ọlasunkanmi Ayeni, sọ fun awọn oniroyin niluu Ilọrin, l’Ọjọbọ, Tọsidee, pe awọn mu awọn afurasi naa pẹlu ibọn ti wọn fi n hu oniruuru iwa ọdaran. O tẹsiwaju pe ọwọ tẹ wọn ni agbegbe ibi ti wọn ti n wa kusa ni abule kan ti wọn n pe ni Agbẹdẹ, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara.
O fi ku un pe nibi ti Alaaji ti n wa ọta ibọn to fẹẹ ra kiri ni ọwọ ti tẹ ẹ, to si ṣokunfa bi wọn ṣe mu John to ta ibọn fun un, ti wọn si tun ba oniruuru ibọn ati awọn ohun ija oloro miiran ni ile rẹ.
Ajọ naa ni ko si ẹni to lẹtọọ labẹ ofin lati maa gbe ibọn kiri, afi ti wọn ba gbe iwe rẹ nikan lo ku. O waa rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara lati maa tu aṣiri ẹnikẹni to ba n gbe ohun ija oloro kiri.

Leave a Reply