Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Nitori ti wọn n sa lẹnu iṣẹ, agunbanirọ mejidinlọgbọn yoo tun ilẹ baba wọn sin ni Kwara
Ajọ to n ri si ọrọ awọn agunbanirọ to n sin ilẹ baba wọn, ẹka tipinlẹ Kwara, ti sọ pe awọn to n lọ si bii mejidinlọgbọn ni wọn yoo tun ilẹ baba wọn sin nipinlẹ naa fẹsun pe wọn sa lọ lasiko ti wọn sinru ilu lọwọ.
Adari ajọ ọhun nipinlẹ Kwara, Arabinrin Francisca Ọlalẹyẹ, lo fi ọrọ naa lede l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nibi ayẹyẹ ipari awọn agunbanirọ niluu Ilọrin. O ni ko si abuja lọrun ọpẹ gbogbo awọn to sa lọ yii, wọn yoo tun ilẹ baba wọn sin nipa lilo ọdun kanmi-in. O tẹsiwaju pe ọpọ awọn ti ko tẹlẹ ofin ati ilana ajọ agunbanirọ ni awọn naa ti koju ijiya to tọ. O fi kun un pe ajọ naa tun fi kun asiko to yẹ ki awọn agunbanirọ to n lọ bii mejilelogun lo siwaju latari awọn oniruuru ẹṣẹ ti wọn ṣẹ.
Ọlalẹyẹ ki awọn to n pari ku oriire, paapaa ju lọ awọn to wa lẹka iwosan, o gbadura pe iwaju ni ọpa ẹbiti wọn yoo maa re si, Ọlọrun yoo si maa tọ wọn sọna ni gbogbo aaye kaaye tabi iṣẹ yoowu ti wọn ba n ṣe.