Nitori to ra ẹru ole, adajọ sọ igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa sẹwọn gbere l’Ekiti

Dada Ajikanje

Ilẹ-ẹjọ giga kan niluu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, ti ju igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa kan, Okubo Aboye, sẹwọn gbere. Ọkọ ti awọn ajinigbe ji gbe ni wọn lo ra, bo tilẹ jẹ pe o mọ pe ẹru ole ni.

ALAROYE gbọ pe mẹkaniiki rẹ, Niyi Ibrahim Afọlabi, lo ta mọto naa fun un, awọn mejeeji si ni adajọ ju sẹwọn gbere.

Agbefọba to ṣiṣẹ iwadii lori ẹjọ naa, Felix Awoniyi, sọ pe awọn eeyan naa ko nnkan ija oloro, wọn si da ọkunrin kan, Moses Agori, lọna, wọn gba mọto

nidii rẹ.

Mọto ọhun ni awọn agbofinro fi imọ ẹrọ wadii rẹ, ti wọn si ba a ninu ọgba ile Okubo.

Ọkunrin naa ko jiyan rara nigba ti awọn agbofinro ko o loju, o ni mẹkaniiki oun lo ta mọto naa foun.

Awọn ajinigbe yii lo gbe mọto ọhun fun Niyi Afọlabi to jẹ mẹkaniiki Okubo pe ko bawọn ta a, toun fi ta ọkọ ti wọn ji ọhun fun un, bo tilẹ jẹ pe iwadii fidi rẹ mulẹ pe o mọ pe ẹru ole ni.

Awoniyi ni iwa ti awọn olujẹjọ hu lodi labẹ ofin iwa ọdaran tipinlẹ naa n lo, bẹẹ lo ni ijiya to gbopọn wa fun un.

Adajọ John Adeyẹye ni iwa ijinigbe ti di nnkan nla ni orileede Naijiria, ati pe ko ni i da lati ma ṣe ojuṣẹ awọn nipa fifi iya jẹ ẹni ti aje iru iwa ibajẹ bẹ ẹ ba ṣi mọ lori. O ni gbogbo ẹri to wa niwaju oun fi han pe igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa naa mọ pe ẹru ole ni ọkọ ti wọn ta fun un. Nidii eyi, oun sọ ọ si ẹwọn gbere.

Bakan naa ni adajọ ju Solomon Ayodele Ọbamoyegun (39), Fẹmi Omiawe (40), Damilọla Ọbamoyegun (20), Bọsẹ Sade Ajayi, (30), George Lucky, (35), Chukuwa Nnamani (22), ati Sunday Ogunlẹyẹ (45), sẹwọn ọdun marun-un lai si owo itanran fun ẹsun ijinigbe.

Leave a Reply