Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Titi dasiko yii ni ipohunrere ẹkun ṣi n lọ laarin awọn oṣiṣẹ ileewosan kan l’Abẹokuta, nitori meji ninu awọn nọọsi wọn lo padanu ẹmi rẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, awọn mẹwaa tun wa lọsibitu ti wọn n gbatọju. Bẹẹ, dẹrẹba to n wa wọn lọ si pati lo n tẹ foonu lori ere, ni mọto ba danu loju ọna marose Eko s’Abẹokuta.
Alaye ti Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, ṣe nipa iṣẹlẹ yii ni pe, ọga kan ninu awọn nọọsi lo n ṣe pati lọjọ Sannde naa, iyẹn ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin yii, ode naa ni wọn n lọ ninu mọto bọọsi ti nọmba ẹ jẹ OG 49 A 07 alawọ funfun kan.
Akinbiyi sọ pe ọkan ninu awọn to yè ninu iṣẹlẹ naa ṣalaye pe bawọn ṣe n lọ ni dẹrẹba to n wa mọto naa n sare ju, yatọ si pe o si n sare yii, o ni niṣe lo tun n tẹ foonu rẹ, ti ko yee wo foonu, bẹẹ, eti ko gbọ meji lẹẹkan ṣoṣo, ohun to fa wahala niyẹn.
Nigba to de ibi kan to daagun (bend), ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ kọja ogun iṣẹju lọjọ naa, ti ko si yee tẹ foonu bo ṣe n wakọ lo padanu ijanu mọto, nigba naa ni mọto awọn nọọsi to n lọ sode yii bẹrẹ si i gbokiti, o si takiti ọhun leralera gan-an bi Akinbiyi ṣe sọ.
Meji ku ninu awọn nọọsi naa, awọn mẹwaa si fara ṣeṣe. Mọṣuari to wa ninu ọgba ọsibitu Jẹnẹra, n’Ijaye, ni wọn ko awọn oku meji naa lọ l’Abẹokuta, nigba ti wọn gbe awọn to ṣeṣe lọ sileewosan Hope, l’Adigbẹ, niluu Abẹokuta, kan naa.
TRACE ba awọn tiṣẹlẹ yii kan daro, o si kilọ fawọn awakọ pe ki wọn yee tẹ foonu bi wọn ba n wa mọto, ki wọn si tẹti si ikilọ ere asaju tawọn ki i yee ṣe fun wọn, nitori awọn ko ṣẹṣẹ maa sọ ọ, k’Ọlọrun jẹ ki wọn gbọ ni.