Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori bi awọn ọdọ kaakiri orileede yii ṣe n pariwo pe kijọba apapọ pa ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn n pe ni SARS (Special Anti-Robbery Squard), iyẹn awọn ọlọpaa ti wọn ya sọtọ lati maa gbogun ti idigunjale, wọn si ti ṣe aimọye iwọde lori ẹ, Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, ti kan saara si awọn olufẹhonu han naa.
Oṣuba ti CP Enwonwu gbe fawọn to fẹhonu han wọnyi ki i ṣe ti pe o fara mọ nnkan ti wọn beere fun, bi ko ṣe nitori pe wọn ṣe kinni ọhun wọọrọ lai la wahala lọ.
Awọn ọ̀dọ́ igboro ’Ibadan ko mu ọrọ naa ni kekere, odidi ọsẹ kan gbako (ọsẹ to kọja) ni wọn fi ṣe iwọde alaafia lati sọ fun gbogbo aye pe awọn ko fẹ ọlọpaa SARS nilẹ yii mọ.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, ni wọn bẹrẹ, nigba ti awọn ọdọ kan ti pupọ ninu wọn jẹ akẹkọọ The Polytechnic, Ibadan, rọ da soju titi, wọn ṣe iwọde ọhun lati orita UI de Eléwúrẹ, laduugbo Sango, n’Ibadan.
Bi wọn ṣe n kora wọn jọ ti wọn n ṣewọde wọọrọwọ lojoojumọ ree titi dọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, nigba ti eeyan bii ẹgbẹrun kan abọ (1,500) rọ di ẹnu ọna abawọle sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ. Wọn ko si tori nnkan meji ṣewọde ọhun ju ọrọ atako awọn ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale yii lọ.
Ọpọlọpọ iwe fifẹ ti wọn kọ oriṣiiriṣii akọle si ni wọn gbe lọwọ lati fi aidunnu wọn han si SARS, wọn ni apaayan lasan lasan ni wọn, bẹẹ lawọn mi-in pe wọn lole, nigba ti awọn kan kọ ọ sori paali ọwọ tiwọn pe ọdaran pọnbele ni wọn.
Bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro ko jẹ ki wọn raaye wọnu sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ pẹlu bi wọn ṣe ti gbogbo ilẹkun abawọle ọgba gbọingbọin, sibẹ, wọn tun fi ọda kọ ọ si ara geeti abawọle nla ọgba naa pe “ẹ fopin si SARS”.
Aarin bii wakati mẹta ni sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ atwọn ohun irinna fi waye lati Bodija si Total Garden lọ si orita UCH, lọna Mọkọla. Yatọ si pe awọn ọdọ to ṣewọde yii pọ laaye ara wọn, ọpọ ninu wọn lo tun gbe mọto lọwọ, ọkọ ayọkẹlẹ olowo nla ti wọn si fi ṣẹsẹ rin ninu iwọde ọhun ko din laaadọta (50). Awọn eeyan naa si mọ-ọn-mọ wa awọn ọkọ ọhun gunlẹ lati fi da gólsìloò silẹ lagbegbe sẹkiteriati ijọba ni.
Sun-kẹre-fa-kẹrẹ ọhun iba ti pẹ to bẹẹ bi ko ṣe bi Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinia Ṣeyi Makinde ṣe kọ lati yọju si wọn. Ọnarebu Ṣeun Fakorede ti i ṣe kọmiṣanna feto ere idaraya ati ọrọ awọn ọdọ nipinlẹ Ọyọ gbiyanju lati ba wọn sọrọ lorukọ gomina, ṣugbọn awọn ọdọ wọnyi pa a lẹnu mọ, wọn ni Makinde funra rẹ lawọn fẹẹ ri, bo tilẹ jẹ pe iyẹn ko pada yọju si wọn.
Nigba ti aṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Ila-oorun Ibadan keji, Ọnarebu Yusuf Adebisi, to tun jẹ ọmọ Alhaji Taye Adebisi Currensi ti i ṣe gbajugbaja onifuji Ibadan nni paapaa gbiyanju lati da awọn olufẹhonu han yii lẹkun, abuku ti wọn fi kan an ki i ṣe kekere, niṣe ni wọn pariwo le e lori titi to fi kuro niwaju wọn.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu fi idunnu ẹ han si bi awọn ọdọ naa ko ṣe ba nnkan jẹ lasiko ti wọn n ṣewọde ọhun, bo tilẹ jẹ pe o sọ fun wọn pe ọga agba ọlọpaa patapata lorileede yii, IG Muhammed Adamu, ti ṣeto lati jẹ ki atunto ba awọn ọlọpaa SARS, dipo fifagile e patapata.