Ọwọ tẹ Adewale to n fi ayederu owo gba ojulowo lọwọ awọn to n ṣe POS n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ afurasi onijibiti kan, Ibrahim Adewale, ẹni to n fi ayederu owo gbowo gidi lọwọ awọn to n ṣe pii-oo-ẹẹsi (POS) l’Ọyọọ.

L’Ojọruu, Wẹsidee, to kọja yii, lawọn ọlọpaa to n yide kiri fun eto aabo nigboro ilu Ọyọ mu ọkunrin naa lagbegbe Owode, nibi ti oun pẹlu ẹni to lu ni jibiti ti jọ n pariwo lera wọn lori.

ALAROYE gbọ pe awọn meji ni wọn jọ n ṣiṣẹ buruku naa, ṣugbọn Ibrahim nikan lọwọ tẹ nigba ti ikeji ẹ ti sa lọ ni tiẹ.

Wọn ni wọn maa n ko ayederu owo lọọ fun awọn to n ṣe POS, ti awọn yẹn yoo si ba wọn san iye ti wọn ba ko kalẹ sinu akanti wọn. Nigba ti awọn onitọhun ba gbiyanju lati nawo ọhun fawọn to da owo mọ ni wọn yoo too mọ pe owo feeki lasan lawọn mu lọwọ.

 

Awọn eeyan buruku wọnyi jafafa debii pe niṣe ni wọn maa n lo akanti kan naa. Ibrahim lo maa n lọọ fi awọn ayederu owo wọn sanwo sinu aṣunwọn wọn. Bi awọn oni POS ba ti san iye to ko wa fun wọn sinu akanti wọn lọrẹ rẹ yoo ti ri atẹranṣẹ lori foonu rẹ pe owo kan ti wọle sinu akanti wọn. Lẹsẹkẹsẹ ni yoo si ti lọọ gbowo ọhun lẹnu ẹrọ Ee-Tii-Ẹẹmu (ATM)

Bi awọn onijibiti yii ṣe n dọgbọn paarọ ayederu owo ọwọ wọn si owo gidi ree kọwọ palaba wọn too segi l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja.

Gẹgẹ bi DSP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ṣe fidi ẹ mulẹ, ayederu owo to jẹ ẹgbẹrun mejidinlọgọrun-un Naira (N98,000) lalagbari eeyan yii ko fun oniṣowo owo lati fi gbowo gidi lọwọ ẹni ẹlẹni lai mọ pe onitọhun da owo buruku mọ

Lẹyin ti awọn ọlọpaa fi ibeere po o nifun pọ ninu iwadii wọn, baba ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta yii jẹwọ pe awọn meji lawọn n ṣiṣẹ ibi naa, ṣugbọn nigba ti yoo fi mu wọn debi ti ẹni keji rẹ yii wa, onitọhun ti sa lọ bamubamu.

O jọ pe bi jagunlabi ṣe duro de owo titi ṣugbọn ti owo ko wọle sinu akanti, ti ko si tun gburoo ẹni keji ẹ lara ti fu u, ti jagunlabi fi na papa bora.

Awọn agbofinro ti n tẹsiwaju ninu iwadii lori iṣẹlẹ yii, laipẹ yii ni wọn yoo si foju afurasi onijibiti tọwọ tẹ yii bale-ẹjọ gẹgẹ bi Ọṣifẹṣọ ṣe fidi ẹ mulẹ lorukọ CP Ngozi Onadeko ti i ṣe ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ.

Leave a Reply