Kazeem Aderohunmu
Ọkan ninu awọn oṣerẹ ilẹ wa, Sotayọ Ṣobọla, ti gbogbo eeyan mọ si Sogaga, naa ti dara pọ mọ awọn oṣere ilẹ wa ti wọn lade lori bayii, oun naa ti diyawo lọọdẹ ọkọ.
Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni oṣere naa gbe aworan rẹ, nibi to ti wọ aṣọ igbeyawo, to si fi oruka sọwọ jade, bo tilẹ jẹ pe ko si ọkọ to fẹ lẹgbẹẹ rẹ.
Bi awọn ololufẹ rẹ ti ri aworan naa ni wọn ti n ki i ku oriire, ti wọn si n rọjo adura le e lori pe Ọlọrun yoo fibẹ gba a, yoo si pese ọkunrin abiro, obinrin abiye fun un.
Ninu foto ti Ṣotayọ gbe jade yii lo ti kọ ọ pe ki i ṣe pe ayẹyẹ igbeyawo ọhun ṣẹṣẹ waye ni, o ni oun kan pinnu lati gbe aworan naa jade lonii, iyẹ lọjọ Ṣatide, ọjọ kẹfa, oṣu kẹta, yii ni.
Ṣugbọn eyi o wu ko jẹ, Sotayọ naa ti kuro ninu awọn oṣere to n wa ọkọ, oun naa ti di iyawo lọọdẹ Mr Somebody ti ẹnikẹni ko ti i mọ bayii. Bẹẹ ni ko sẹni to le sọ ọjọ tabi asiko pẹlu ibi ti igbeyawo naa ti waye, bonkẹlẹ lo fi ṣe.
Ṣugbọn pẹlu ẹ naa, adura lawọn ololufẹ rẹ pẹlu awọn oṣere ẹgbẹ ẹ n ṣe fun un.