Oṣere tiata kọle tuntun fun iya ẹ

Faith Adebọla, Eko

Idunnu ti ṣubu l’ayọ fun gbaju-gbaja oṣere-binrin adẹrin-in poṣonu ilẹ wa nni, Funmi Awẹlẹwa, tawọn eeyan mọ si Mọrili.Ki i ṣe idunnu bin-in-tin rara, tori bi omije ayọ ṣe n ja bọ loju oṣere apọnbeporẹ, awẹlẹwa, gẹgẹ bii orukọ rẹ yii, bẹẹ lawọn ololufẹ rẹ n ki i ku oriire, ti wọn si n ba a yọ. Eyi ko sẹyin ile awoṣifila kan to kọ fun mama rẹ.

Ṣe inu ẹni ki i dun ka pa a mọra, ninu fidio kan ti Funmi gbe sori opo ayelujara Instagiraamu rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii lo ṣafihan bo ṣe bẹrẹ iṣẹ ile kikọ naa, bi awọn birikila ṣe n ba iṣẹ lọ wẹrẹwẹrẹ nibẹ, titi ti ile naa fi di odidi, ti wọn fi ọda to rẹwa kun un, ti ile naa si ri miringindin.

Labẹ fọto ile ọhun, o kọ ọrọ sibẹ pe:
‘Alihamudulilaah, mo ki mọlẹbi mi ku oriire o. Ile yii waa jẹ iṣẹ pataki kan nigbesi aye mi, mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o lo mi lati tun itan idile mi kọ. Mi o rọgbọn da si i, mo ni lati fẹmi imoore han si ohun t’Ọlọrun ti ṣe laye wa ni. Ẹbun leyi jẹ, mo fi i ta mama mi atawọn ẹgbọn ataburo mi lọrẹ ni, tori emi tun maa bẹrẹ irinajo alarinrin mi-in lọla.

Mo ki gbogbo mọlẹbi Babalọla ku oriire o.”

O tun kọ lẹta iwuri jan-an-ran-jan-an-ran kan si mama rẹ, apa kan lẹta naa ka pe:
“Maami, mo dupẹ ẹyin ni ibi akọkọ ti ọkan mi maa n pe ni ile mi. Ọwọ yin tẹ ẹ kọkọ fi gbe mi lati ibẹrẹ aye mi naa lẹ ṣi fi di mi mu nigba ti nnkan ko ba ye mi mọ. Mọmi mi ọwọn, ẹ ma binu fun gbogbo aniyan ti mo maa n ko yin si lawọn igba ti mo ba ṣaṣiṣe, ti mo si n kẹkọọ ninu aṣiṣe mi, mo ri i pe ẹ ṣi n ran mi lọwọ lati gbe mi ro. Mo nifẹẹ yin gan-an, mo si dupẹ lọwọ yin jọjọ.

“O wu mi lati dun yin ninu jalẹ igbesi aye yin ni, latari gbogbo awọn nnkan meremere tẹ ẹ n ra fawọn ẹgbọn ataburo mi, ni gbogbo igba tẹ ẹ ti ta aṣọ atata yin lati le rowo ra ounjẹ fun wa, tori nnkan to daa ju lọ lẹ fẹ fun wa nigbesi aye. Mo dupẹ pe ẹ na apa yin ko le ṣee ṣe fun mi lati fo, bo tilẹ jẹ pe nigba ti mo ba tun fẹẹ ja bọ, kia lẹ ti maa di mi mu. Bi mo ṣe n goke, ti mo n fo lọ soke rere, ko ṣẹyin yin, ọla yin ni.

Lawọn igba ti mo ba fẹẹ dupẹ lọwọ yin, ṣugbọn ti mi o sọrọ, mo lero pe ẹ mọ, mo dupẹ lọwọ yin gidi o, mọinmi. Mo gbadura pe k’Ọlọrun lọra ẹmi yin kẹ ẹ le fọkan balẹ gbadun igbe aye ọtun to bẹrẹ yii. Ma a tọju yin dọba, ma a fowo sikẹ yin, ẹ ma mikan rara, Iya Mọrili. Ọlọrun wa pẹlu wa.”

Lẹyin eyi lobinrin naa waa kọ ọrọ idupẹ sawọn eeyan, o ni:

“Mo tẹwọ ọpẹ nla, ọpẹ akanṣe latinu ọkan mi wa, si Ọlọrun Olodumare to n mu ki nnkan ṣee ṣe o. Gbogbo ẹyin tẹ ẹ ṣatilẹyin fun mi, tẹ ẹ jẹ ki ala mi wa si imuṣẹ, mo dupẹ gidigidi lọwọ yin o. Gbogbo ẹyin tẹ ẹ n polowo ọja wa, atẹyin purodusa ti mo n ba ṣiṣẹ, emi ree o, mo waa dupẹ lọwọ yin ni o. Gbogbo ẹyin ileeṣẹ tẹ ẹ ti fi mi ṣe aṣoju yin, ti mo n polowo ọja fun, mo dupẹ, ọpẹ o tan o. Gbogbo ẹyin tẹ ẹ n gbaruku ti okoowo wa, tẹ ẹ n ra ọja wa, mo dupẹ gidigidi o.”

Awẹlẹwa ko fi ọpẹ rẹ naa mọ sibẹ o, o tun dupẹ lọwọ ọkunrin kan ti ko darukọ rẹ, o lọkunrin naa ni onilu to wa labẹ omi ti irawe oun fi n jo bii okoto loke odo. Awọn ololufẹ rẹ kan ti n sọ pe afẹsọna Funmi Awẹlẹwa ni ọkunrin to n paṣamọ mọ yii. Bayii lo ṣe sọrọ naa:

“Si ọkunrin kan to n dẹrin-in pẹẹkẹ mi ni kọrọ, mo dupẹ gidigidi lọwọ ẹ o. O ṣee gan-an, mi o ni i jọra mi loju o.

“Mo dupẹ lọwọ gbogbo eyin eeyan to mu ki eyi ṣee ṣe, mo dupẹ mo tọpẹ da.

“Mo ki gbogbo ẹyin mọlẹbi mi ku oriire yii o.”

Bi Mọriri ṣe n dupẹ adu-i-du-tan yii, bẹẹ lawọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ bii Bukunmi Oluwaṣina, Wunmi Ajiboye, Sikiratu Sindodo, Biọla Adebayọ (Eyin Ọka), Aisha Lawal, Fẹmi Adebayọ, Adeniyi Johnson, Kunle Afod, Bimbọ Afolayan, Bukọla Adeẹyọ, Mo Bimpe, atawọn ololufẹ rẹ mi-in n ba a yọ, wọn n kọ ọrọ oriṣiiriṣii nnkan lati ki i ku aṣeyọri ati oriire naa. Awọn kan tun kan saara si i pe ọmọ gidi ni, wọn ni nnkan daadaa lo ṣe bo ṣe fi ile ringindin naa sọri ọlọkọ to wa a wa saye, tori iya ni wura.

Ọgọọrọ lawọn to si tun ki arẹwa yii fun ti ayẹyẹ ọjọọbi rẹ, tori lasiko ọjọọbi ọhun lo ṣile tuntun, bẹẹ loun naa gbe awọn fọto to joju-ni-gbese loriṣiiriṣii soju opo ayelujara rẹ ọhun.

Wọn ṣadura fun un pe eleyii ko ni i jẹ ipẹkun oore fun un, ọpọ nnkan meremere ni yoo ṣẹlẹ si i lọjọ iwaju.

Leave a Reply