Oṣere tiata yii pariwo: Ẹ gba mi o, latọjọ ti mo ti ṣojọọbi mi ni itẹkuu lawọn oku ti n yọ mi lẹnu

Monisọla Saka

Kayeefi! Inu iboji larakunrin yii ti ṣe ọjọ ibi ẹ.
Oṣerekunrin ilẹ Ghana kan to ṣayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ni itẹ oku laipẹ yii ti pariwo pe awọn isinku ọrun n yọ oun lẹnu.
Ọlọjọ ibi ọhun torukọ ẹ n jẹ Nkrumah Samuel, ti pupọ awọn eniyan n pe ni Remes Kay, atawọn ọrẹ ẹ ni wọn ko si aṣọ funfun nẹnẹ lakooko ti wọn n dawọọ idunnu ọjọ ibi ẹ ninu iboji awọn oku.
Lori aga ọlọla kan ti wọn ṣe lọṣọọ ni wọn to oniruuru ohun mimu si, ti wọn si gbe akara oyinbo ti ọlọjọ ibi fẹẹ ge si aarin saree bi wọn ṣe n ṣajọyọ.
Ori saree yii ni pupọ awọn alejo to wa nibẹ fidi le gẹgẹ bi ko ṣe si aga ẹyọ kan bayii nibẹ fun ẹnikẹni lati jokoo.
Lati igba naa ni Nkrumah ti sọ pe aye oun ko ri bakan naa mọ lati igba ti oun ti ṣe pati ọhun tan.
Nigba to n sọrọ nibi ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu Abena Gold, oṣere naa ni awọn oku ko fi oun lọkan balẹ latigba toun ti ṣenawo ni iboji wọn.
Remes Kay ṣalaye fun ẹni to n fọrọ wa a lẹnu wo pe, idi pataki ti oun fi lọọ ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi oun ni itẹ ni lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe ọjọ ibi wa ki i kan an ṣe ọjọ ti ọjọ ori wa lekan si i tabi pe a tun ti dagba ju ti eṣi lọ, ṣugbọn to tun tumọ si pe ọjọ ori wa n dinku ninu ọjọ ati ọdun ta a fẹẹ lo laye, ati wi pe, ọjọ ibi wa n ran wa leti pe a ti n sun mọ koto ni.
O tẹsiwaju pe, awọn nnkan abami ati ohun ibẹru loun ti n ri latigba toun ti ṣe ọjọ ibi oun yii, eyi lo jẹ koun kuku gbagbọ pe awọn oku ti n lepa ẹmi oun.
O ni nibi toun ti kọkọ fura ni nnkan to ṣẹlẹ ki awọn too kuro ni itẹ oku lọjọ naa, nigba ti yọtọmi ọjọ ibi yii n lọ lọwọ. Nkrumah loun yọ oruka lọwọ lati kẹnu ifẹ si ọrẹbinrin oun pe oun fẹẹ fi i ṣaya, o ni, bi oun ṣe kunlẹ lati beere boya yoo fi oun ṣe ade ori ẹ, niṣe ni ọrẹbinrin oun yii diju mọri lọ gbari, bẹẹ lo tun gbọwọ le aya lọgangan ibi ti ọkan wa lara eniyan, o ni oun ro pe inu ẹ dun ladunju ni, afi bo ṣe di gbii, to wo lulẹ lojiji, to si daku lọ rangbọndan.
Gbogbo awọn ti wọn wa nibẹ lati waa ba a dawọọ idunnu sare si obinrin naa lati ṣugbaa ẹ, ni wọn ba sare gbe e digbadigba wọnu ọkọ ambulansi ti wọn fi n gbe alaisan ati oku lọ sile iwosan.
Bi gbogbo nnkan ṣe dojuru yii, niyi, oju-ẹsẹ ni wọn sare gbe obinrin naa lọ sileewosan pẹlu ọkọ ambulansi ti wọn fi gbe ọmọ ọlọjọ ibi pẹlu posi wa si iboji oku to ti ṣọjọọbi.
Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, ọrẹbinrin ẹ ṣi wa nile iwosan to ti n gba itọju.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: