Oṣiṣẹ banki kowo awọn onibaara jẹ l’Abẹokuta, nile-ẹjọ ba sọ ọ sẹwọn oṣu kan aabọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Oṣiṣẹ banki kereje (Micro finance) ni Ọgbẹni Philips Ogorome, ẹni ọdun mọkanlelogoji (41) ni. Ṣugbọn iwa to hu nileeṣẹ naa to wa ni Kutọ, l’Abẹokuta, ti sọ ọ dero ẹwọn bayii, nitori wọn lo ko miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna ọgọrin naira (2.8m) ti i ṣe owo awọn onibaara jẹ.

Kootu Majsireeti Ake, l’Abẹokuta, ni Adajọ O.T Ayọbolu, ti paṣẹ pe ki Philips lọọ ṣẹwọn ọdun kan aabọ, iyẹn lọsẹ to kọja yii ti igbẹjọ waye.

Ṣaaju ni Agbefọba, Matthew Famuyiwa, ti ṣalaye fun kootu pe oṣu karun-un, ọdun 2019, ni olujẹjọ bẹrẹ si i gbowo lọwọ awọn onibaara banki NPF Micro Finance to n ba ṣiṣẹ, pẹlu adehun pe oun n ko owo naa pamọ fun wọn bo ṣe yẹ ni. Koda, o n fun wọn ni risiiti to n ṣafihan owo to n gba lọwọ wọn naa, ṣugbọn kaka ko kowo naa sapo ileeṣẹ, apo ara rẹ lo n ko o si.

Agbefọba Famuyiwa sọ pe bayii ni Philips ṣe gba owo lọwọ onibaara mẹtalelọgbọn, apapọ owo naa si jẹ miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna ọgọrin naira.

Yatọ si eyi, agbefọba ṣalaye pe kaadi owo awọn onibaara marundinlogoji ni olujẹjọ yii tun ji ko pamọ, ti ko jẹ ki ọwọ awọn alaṣẹ banki to o rara, ki wọn ma baa le ṣe iwadii ibi ti owo awọn eeyan naa wọle si.

Awọn iwa yii ta ko ofin ipinlẹ Ogun ti wọn ṣe lọdun 2006, bo tilẹ jẹ pe Philips loun ko jẹbi.

Adajọ Ayọbolu sọ pe gbogbo ẹri lo foju han pe olujẹjọ jẹbi ẹsun mẹrindinlogoji ti wọn fi kan an, eyi ti ole jija ati didari owo olowo sapo ẹni jẹ koko ninu ẹ.

O paṣẹ pe ki wọn maa gbe ọkunrin naa lọ sọgba ẹwọn, yoo si lo ọdun kan aabọ nibẹ. Aaye owo itanran ko yọ.

 

 

Leave a Reply