Ọṣinbajo, Dapọ Abiọdun, Ọṣọba tun iforukọsilẹ wọn ṣe lẹgbẹ APC Ogun

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Igbakeji Aarẹ orilẹ-ede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo, Gomina Dapọ Abiọdun ati Oloye Oluṣẹgun Ọṣoba ti tun iforukọsilẹ wọn ṣe lẹgbẹ oṣelu APC. Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹsan-an, oṣu keji, ọdun  yii, ni wọn gbe igbesẹ naa nipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bo ṣe jẹ pe iforukọsilẹ ti bẹrẹ kaakiri ninu ẹgbẹ to n ṣejọba Naijiria lọwọ lawọn ipinlẹ, eyi lo mu Ọjọgbọn Ọṣibanjo wa si ilu abinibi rẹ ti i ṣe Ikẹnnẹ, nibi to ti ṣe atunṣe iforukọsilẹ naa ni Wọọdu kin-in-ni, Yuniiti kẹta, Egunrege, nijọba ibilẹ Ikẹnnẹ.

Bakan naa ni Gomina Dapọ Abiọdun forukọ tiẹ silẹ lẹẹkeji ninu ẹgbẹ APC. Wọọdu kẹta, Ipẹru Rẹmọ, nijọba ibilẹ Ikẹnnẹ kan naa, ni Gomina ti forukọ silẹ, nigba ti Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba fi tiẹ silẹ nileewe alakọọbẹrẹ Ṣodubi, ni Wọọdu keje, ẹkun idibo kẹta, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi/Owode.

Nigba to n sọrọ, Ọṣinbajo sọ pe inu oun dun lati tun forukọ silẹ lẹgbẹ APC, o ni igbesẹ yii lo maa n jẹ ki ẹgbẹ mọ awọn eeyan to jẹ olutẹle, ọna kan si tun ni lati ba wọn sọrọ. O ni igbaye-gbadun ọmọ ẹgbẹ lo jẹ ẹgbẹ Onigbaalẹ logun, nitori ẹgbẹ awọn eeyan ẹsẹkuuku ni.

Ninu ọrọ rẹ, Gomina Dapọ Abiọdun gboriyin fun Igbakeji Aarẹ ati Buhari, fun bi wọn ṣe lọ si orirun wọn lati tun iforukọsilẹ lẹgbẹ wọn ṣe. Dapọ Abiọdun sọ pe igbesẹ yii yoo seso rere nipinlẹ Ogun, o fi kun un pe awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun yoo ṣara jọ.

Awọn mi-in to tun ba Ọṣinbajo ati Gomina Dapọ Abiọdun kọwọọrin lọjọ naa ni: Gomina ipinlẹ Niger to tun jẹ alaga iforukọsilẹ ẹgbẹ APC, Alaaji Abubakar Sani Bello, ati Sẹnetọ Lawan Shuaib.

Leave a Reply

//betzapdoson.com/4/4998019
%d bloggers like this: