Oṣu mẹfa sẹyin ni dokita ti sọ fun mi pe ọmọ mi maa ku- Ebenezer Obey

Monisọla Saka

Agbalagba olorin juju to ti di ajihinrere ati olorin ẹmi bayii, Ebenezer Obey-Fabiyi, ti ṣalaye pe o ku bii oṣu mẹfa ti ọmọ oun to ṣalaisi lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, maa ku ni dokita ti sọ fun oun.

Lasiko ti Obey n fi ẹdun ọkan han lori iku Ọlayinka, ọmọ ẹ, lo sọ eleyii, koda, o fi kun un pe oun sa gbogbo ipa oun gẹgẹ bii abiyamọ tootọ lati ba a ja fitafita lori idojukọ rẹ yii, ṣugbọn to ni gbogbo rẹ ja si pabo. Ninu atẹjade to fi lede lati ẹnu maneja agba ninu ileeṣẹ rẹ, Ọgbẹni Tunji Ọdunmbaku, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lo ti sọrọ naa.

Obey ni, “Awọn dokita oniṣegun oyinbo pe mi loṣu mẹfa sẹyin pe Yinka o ni ju oṣu mẹfa lọ mọ lati lo laye. Iroyin aburu ati ibanujẹ gbaa ni fun abiyamọ lati gbọ pe ọmọ ẹ maa ku.

“Mo pada lọ sọdọ ẹmi mimọ lati kọ mi loun ti mo maa ṣe, abajade ọrọ mi pẹlu ẹmi mimọ si ni ajọ ti a fi lelẹ yii.

Oriṣiiriṣii ikini ibanikẹdun ni mo ti gba latọdọ tolori tẹlẹmu. Ẹ ṣeun, mo dupẹ pupọ fun ifẹ yin”

Isinmi ni Obey lọ fun loke okun nigba ti iroyin iku Ọlayinka kan an lara.

Ebenezer Obey dupẹ lọwọ awọn ọrẹ ọmọ ẹ to ṣalaisi yii fun ilakaka ati aduroti wọn, bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ Shina to jẹ ọmọkunrin ẹ to dagba ju fun amujoto ati ọrọ ibi to ṣe pẹlu awọn aburo lẹyin rẹ fun itọju Ọlayinka titi ti ọlọjọ fi de.

Bakan naa ni baba yii tun dupẹ lọwọ awọn pasitọ, alagba ijọ ati gbogbo ẹbi Decross Ministry, fun gbogbo nnkan ti wọn ṣe.

O tun sọ ọ di mimọ pe oun ti ṣe ifilọlẹ ajọ to n gbogun ti ọti amuju ati egboogi oloro ni lilo, iyẹn ‘Freedom from Alcoholism and Drug Addiction Ministry (FADAM), lati gbogun ti ọti àmuyíràá laarin awọn ọdọ orilẹ-ede Naijiria.

Ajọ yii lo ṣalaye pe o jẹ ọkan lara ipa toun naa ṣa lati pawọ-pọ gbogun ti ilokulo oogun oloro ati ọti laarin awọn ọjẹwẹwẹ ilẹ yii ati loke okun.

Obey-Fabiyi ṣalaye siwaju pe ajọ toun ṣẹṣẹ ṣe ifilọlẹ rẹ yii yatọ si Decross Gospel Mission ati Ebenezer Obey Evangelical Ministry, to ti wa tẹlẹ.

Ni UK, lorilẹ-ede awọn alawọ funfun, lo ni awọn ti ṣefilọlẹ ajọ tuntun yii lati yi irora iku ọmọ oun pada si ileeṣẹ ọna abayọ fawọn ẹbi ati obi awọn ọdọ ti wọn n la iru nnkan bayii kọja.

Gbajugbaja olorin yii ni ilakaka awọn ni lati la awọn ọdọ lọyẹ lori ewu to wa ninu ilokulo oogun oloro ati ọti amuju. Bẹẹ lo tun ṣalaye pe FADAM yii wa lati ran awọn ẹbi ati obi  awọn ọmọ ti ilokulo oogun ti sọ di idakuda lọwọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Yoo mu ki wọn bori ipenija wọn, ki wọn si tibẹ di ọmọ rere lawujọ.

Lẹẹkan si i, mo dupẹ, mo si mọ gbogbo iṣẹ ibanikẹdun ti wọn ran si mi loore, ṣugbọn mo fẹ kaa yi ibanikẹdun yii pada si adura lati ran ileeṣẹ tuntun yii lọwọ lori awọn ti wọn wa ninu irora ilokulo oogun ati ọti lile ni mimu”.

Nigba to mu ọrọ lati inu ẹsẹ Bibeli, o ni, “Ninu iwe Joobu, ori kejilelogun, ẹsẹ kọkanlelogun, ni Oluwa ti ni, ‘Lọ duro ti Oluwa, ire yoo si tọ ọ wa. Fi ọti mimu silẹ, yago fun ilokulo oogun. Jesu fẹran rẹ”.

Ebenezer Obey waa fi awọn ololufẹ rẹ lọkan balẹ pe iṣẹlẹ yii, bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ buburu ni, oun ko ni i jẹ ko jẹ idiwọ foun nibi ere, bẹẹ lo ni gbogbo eto to ti wa nilẹ tẹlẹ loun ko ni i jẹ ko mu ipalara ba.

Leave a Reply