Adefunkẹ Adebiyi
Ọgbẹni Igbakeji Aarẹ, njẹ o mọ pe iwọ lo daa ju ninu ẹyin tẹ ẹ fẹẹ dupo aarẹ lẹgbẹ yin?
Eyi ni ibeere ti gomina ipinlẹ Niger tẹlẹ, Mu’azu Babangida Aliyu, beere lọwọ Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun, oṣu kin-in-ni yii, lasiko to n sọrọ nibi eto kan nipinlẹ Kano.
Babangida sọ pe ko si ondije kankan lẹgbẹ APC to daa to Ọjọgbọn Ọṣinbajo. O ni awọn eeyan keeyan olowoogbo kan ko ni i rọwọ mu ninu ibo aarẹ 2023 yii o, koda ki wọn fowo ṣe e.
“Ko si bo ṣe le lowo to, ẹ jẹ ko gbe owo ẹ wa, a maa gba a” Bẹẹ ni Babangida Aliu wi.
Ọkunrin ọmọ ipinlẹ Niger naa ṣapejuwe Igbakeji Aarẹ gẹgẹ bii ondije kan ṣoṣo to mọ Naijiria daadaa, tawọn eeyan si tẹwọ gba kaakiri orilẹ-ede yii, lai fi ti ẹya ṣe.
Bakan naa ni Emir ilu Lafia, Adajọ-fẹyinti Sidi Bage naa n lulu atilẹyin fun Ọṣinbajo. Nibi ayẹyẹ naa loun paapaa ti sọ pe “Ọgbẹni Igbakeji Aarẹ, gbogbo ibi to o ba n lọ, a o maa ba ọ lọ”
Emir Lafia sọ ọ di mimọ pe ipinlẹ Nasarawa yoo ṣe gbogbo atilẹyin to tọ fun Yẹmi Ọṣinbajo lati di aarẹ lọdun to n bọ.
O ni kijọba apapọ tubọ so okun aabo le si i lorilẹ-ede yii, paapaa l’Oke-Ọya, nibi ti ijinigbe ti di nnkan gbogbo igba. Emir ni kijọba ro awọn ọba lagbara kawọn naa le sa agbara wọn lori aabo to sọnu yii.
Ni ti Babangida Aliyu, awọn eeyan ni ohun to n sọ naa ṣi le yipada, ṣebi oloṣelu ni. Awọn kan sọ pe Aṣiwaju Tinubu lo n dọgbọn pe ni olowoogbo, wọn ni biyẹn ba si gbowo fun un gẹgẹ boun naa ṣe sọ, yoo gba a.