Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Oṣogbo, ti fagi le ẹjọ ti Ọmọọba Dọtun Babayẹmi pe lori ẹni ti yoo jẹ ojulowo oludije funpo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.
Adajọ kootu naa, Onidaajọ Nathaniel Ayọ-Emmanuel, sọ pe Senetọ Ademọla Adeleke ni oludije ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa dibo yan lasiko idibo abẹle wọn to waye kọja l’Oṣogbo.
Ayọ-Emmanuel dajọ pe eto idibo abẹle ti awọn igun kan ninu ẹgbẹ naa ṣe ni WOCDIF, lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, ninu eyi ti wọn ti kede Dọtun Babayẹmi gẹgẹ bii oludije wọn ko lẹsẹ nilẹ rara.
A oo ranti pe ṣaaju idibo abẹle wọn ni wahala ti bẹ silẹ laarin wọn, awọn agbaagba ẹgbẹ ba awọn oludije mẹfa sọrọ pe ki wọn fun Babayẹmi laaye lati jẹ oludije ti wọn fẹnu ko si, wọn si gba, ṣugbọn Ademọla Adeleke ṣe tiẹ lọtọ.
Awọn igun Babayẹmi ṣe idibo tiwọn ni WOCDIF, nigba ti awọn Adeleke ṣe tiwọn ni ori papa iṣere nla ti ilu Oṣogbo. Lẹyin ti awọn alakooso apapọ ẹgbẹ naa l’Abuja fun Adeleke ni satifikeeti ọmọ oye ni Babayẹmi mori le ile-ẹjọ, ṣugbọn ni bayii, ile-ẹjọ ni ẹjọ to pe ko lẹsẹ nilẹ.