O ṣee ṣe ka tun se awọn eeyan mọle lẹẹkan si i nitori korona-Sanwoolu

Aderohunmu Kazeem

Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ, o ṣee ṣe ki ijọba ipinlẹ Eko tun ṣofin konilegbele bi awọn to ni arun korona ba tun pọ si i nipinle naa.

Ọga agba lẹka to n ba araalu sọrọ nileeṣẹ eto ilera, Tubọsun Ogunbanwo lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade kan lati ileeṣẹ naa. Ọkunrin to gbẹnu Komiṣanna fun eto ilera, Ọjọgbọn Akin Abayọmi, sọrọ yii sọ pe ọpọ awọn orileede lo ti tun ṣofin konilegbele nitori korona to tun ti pada de lẹẹkeji.

O fi kun un pe bi awọn eeyan ko ṣe tẹle ofin ati alakalẹ ijọba lori idena korona yii le mu ki ijọba kede igbele korona lẹẹkeji nipinlẹ Eko.

Abayọmi kilọ fawọn araalu pe o ṣe pataki ki wọn tẹle gbogbo ofin ati ilana pẹlu ikilọ ijọba lori idena korona yii lati dena ohun to ṣokunfa igbele korona lọjọsi.

Kọmiṣanna ni bi korona ba tun fi le ṣẹ yọ nipinlẹ Eko, a jẹ pe gbogbo eto ti awọn ṣe lati fun araalu lanfaani lati maa lọ kaakiri ati bi awọn ṣe da ọrọ aje pada si bo ṣe wa tẹlẹ lawọn yoo fagi le.

O ni ki awọn eeyan ko ọkan kuro ninu igbagbọ pe korona ti lọ, nitori ko sohun to jọ bẹẹ rara. O ni igbagbọ naa lewu, eyi to mu n ki awọn eeyan kọ awọn ohun eelo to le wa fun aabo wọn silẹ.

2 thoughts on “O ṣee ṣe ka tun se awọn eeyan mọle lẹẹkan si i nitori korona-Sanwoolu

Leave a Reply