O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Kayọde Fayẹmi, Kayọde Fayẹmi, fẹsọ ṣe

Bi gbogbo aye ko ba ti i mọ ohun ti Gomina ipinlẹ Ekiti bayii, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, fẹẹ ṣe, ọkunrin naa ati awọn ti wọn sun mọ ọn yoo ti mọ lọkan ara wọn. Bi Fayẹmi ba fẹẹ di aarẹ Naijiria, yoo buru ṣa ko jẹ awọn Hausa ni yoo kọkọ maa sọ fun wa. Iyẹn to ba jẹ ohun to fẹẹ ṣe niyẹn o. Ṣugbọn ọrọ ti Sultan Ṣokoto ati Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai, sọ lọsẹ to kọja yii, ọrọ kan to ko awọn onilaakaye lọkan soke ni. El-Rufai lo pe Fayẹmi sibi ayẹyẹ ṣiṣi ile ikowee-pamọ-si kan ti wọn kọ ni orukọ Sardauna Sokoto tẹlẹ, Alaaji Ahamadu Bello. Nibẹ ni Fayẹmi ti jẹ alejo pataki, oun lo si sọrọ nibẹ. Bo ti sọrọ tan ni Sultan ni ọmọ kan ti Sultan bi sita ni Fayẹmi, awọn si ti gba a wọle gẹgẹ bii ọmọ baba awọn, iyẹn Ahamadu Bello. O ni gbogbo anfaani to ba tọ si ọmọ Ahmadu Bello ti tọ si Fayẹmi ni gbogbo ilẹ Hausa lati igba naa lọ. Nigba ti El-Rufai naa yoo si sọrọ, o ni ẹni to ba mọ awọn daadaa, yoo mọ pe awọn ki i deede peeyan wa si iru awujọ pataki bẹẹ. O ni o nidii pataki kan ti awọn fi pe Fayẹmi pe ko wa o, idi pataki naa yoo si han si gbogbo aye laipẹ jọjọ. Ko si idi pataki kan naa nibẹ ju pe wọn pe Fayẹmi ko maa bọ waa du ipo aarẹ Naijiria ni 2023 lọ. Wọn n sọ pe awọn fẹẹ kọyin si Tinubu, Fayẹmi to jẹ ọmọ awọn lawọn fẹẹ mu. Bi wọn ba ṣe eleyii, ko ha jẹ pe Fayẹmi yoo kọyin si ọga rẹ, wọn yoo si di ọta, o si ṣee ṣe ki ọrọ naa sọ ọ di ọta awọn ọmọ Yoruba mi-in. Ṣugbọn njẹ ohun ti wọn sọ pe awọn fẹẹ fun Fayẹmi yii le to o lọwọ ṣa. Awọn ti wọn ba Tinubu jẹ, ti wọn ba Tinubu mu, ti wọn leri fun un pe awọn yoo fun un ni nnkan, to waa di asiko yii, ti wọn ko fẹẹ fun un ni kinni ọhun mọ, ti wọn ni Fayẹmi lawọn fẹẹ fun, njẹ ki i ṣe ẹtan bayii bi o! Awọn yii kan naa ni wọn ba Abiọla jẹ, ti wọn ba a mu, ti wọn ni awọn yoo fun un ni nnkan, nigba ti asiko to, wọn ko fun un ni kinni naa mọ o. Ileri ti Fulani ba ṣe nidii oṣelu ati ipo agbara ko to o tẹle o, nitori ẹ, ki Kayọde Fayẹmi fẹsọ ṣe.

 

Awọn wo ni wọn n tan Jẹgẹdẹ bayii na?

Kaka ki Eyitayọ Jẹgẹdẹ ko iwọnba owo to ba ku lọwọ ẹ lẹyin inawo rẹpẹtẹ to ṣe lori idibo ipinlẹ Ọndo jọ, ko maa fi ṣe aye ẹ, ọkunrin naa ti tun gba awọn kan laaye lati maa tan oun, o loun n lọ sile-ẹjọ, ojooro nibo ti wọn di to gbe Rotimi Akeredolu wọle. Ọmọ ẹgbẹ PDP ni Jẹgẹdẹ, orukọ ẹgbẹ naa lo si fi du ipo gomina, ṣugbọn ko wọle. Koda, Ajayi to n ṣe igbakeji gomina lọwọlọwọ, toun naa lọ si inu ẹgbẹ oṣelu mi-in, ko wọle bakan naa, Akeredolu ti APC lo wọle. Ọpọlọpọ nnkan ni yoo mu Akeredolu wọle, akọkọ ni pe oun ni gomina to wa ni ipinlẹ naa lọwọlọwọ, ẹẹkeji si ni pe ẹgbẹ oṣelu wọn, APC, lo n ṣẹjọba apapọ. Ọpọ agbara lo wa lọwọ Akeredolu ati ẹgbẹ oṣẹlu rẹ, ohun to si jẹ ko wọle naa niyẹn. Jẹgẹdẹ gbiyanju, nitori oun naa ni ibo to pọ daadaa. Boya ka ni ko si ija ninu PDP, tabi ko jẹ Ajayi Agboọla to kọkọ wa si ọdọ wọn duro sibẹ ni, o ṣee ṣe ki Jẹgẹdẹ wọlẹ. Ṣugbọn ọro ti ri bo ti ri, koda, awọn ọlọgbọn inu PDP mọ pe ko si bi Jẹgẹdẹ ti ṣe fẹẹ wọle. Bi ibo ba waye bayii to si lọ, ohun to maa n dara fun ẹni to ba kuna ni lati fọwọsọwọ pẹlu ẹni to ba wọle, iyẹn to ba ṣe pe ire ipinlẹ wọn lawọn mejeeji jọ n wa. Ohun ti yoo mu ilọsiwaju ba ipinlẹ naa niyẹn. Nidii eyi, ko si ohun to yẹ ki Jẹgẹdẹ wa gba ile-ẹjọ lọ, to ba jẹ loootọ, ire ati daadaa ipinlẹ Ondo lo n wa. Eyi to fẹẹ ṣe yii, wọn yoo tubọ tun bẹrẹ si i ko ọkan awọn eeyan ibẹ soke lasan ni, bẹẹ ni ijọba ko si ni i roju raaye lati ṣe awọn ohun to yẹ ko ṣe. Nigbẹyin, Jẹgẹdẹ yoo pada ja bọ naa ni, ki waa ni anfaani iko-araalu-lọkan-soke yii si. Bẹ ẹ ba ri Jẹgẹdẹ, ẹ sọ fun un ko ma fi akoko ati owo ẹ ṣofọ, ko jokoo jẹẹ jare.

 

Mojisọla, aṣofin Eko, alasọjaamu

Lara ohun ti ko dara to n ṣẹlẹ si wa ni Naijiria, ati ni ipinlẹ rẹ gbogbo ni yiyan awọn eeyan ti wọn ko kun oju oṣuwọn si ipo giga. Ohun to maa n ṣẹlẹ ni pe ko si bi ipo naa ti le ga to, awọn eeyan yii yoo mu ipo naa wa silẹ ni, nipa ọrọ to ba n ti ẹnu wọn jade, ati iwa ti wọn ba n hu si araalu. Orukọ aṣofin to n ṣoju wọn ni agbegbe Amuwo Ọdọfin ni Mojisọla Alli-Macauley. Nigba tọrọ wahala to ṣẹlẹ lọsẹ to lọ lọhun-un di ohun ti wọn n jiroro nileegbimọ aṣofin, ọrọ to tẹnu aṣofin yii jade lo ku ti gbogbo aye n gbe kiri. O ni awọn ọdọ ti wọn n pariwo kiri yii, ọpọlọpọ wọn lo jẹ oogun oloro ni wọn n mu kiri, ki wọn mu igbo, ki wọn mu kokeeni, lo ba aye wọn jẹ, ki i ṣe nitori pe wọn ko niṣẹ lọwọ. O ni ki i ṣe Naijiria nikan ni awọn ọdọ wọn ko ti nisẹ lọwọ, arun to n ṣe wọn ni Naijiria yii naa n ṣe wọn l’Amẹrika, awọn ọmọ wọn ko si tori ẹ ya pooki sigboro, igbo lo n daamu awọn ọmọ tiwa nibi. Ọrọ yii bi gbogbo eeyan ninu, paapaa awọn ọdọ, wọn si sọrọ si obinrin naa daadaa. Ṣe ki i ṣe pe oun nikan lo wa nile-igbimọ, o kan jẹ oun lọrọ to sọ buru ju ni, ti ko si ba ọrọ tawọn eeyan n sọ nipa awọn ọdọ wa mu. Amẹrika tabi ilu oyinbo ti oun n sọ pe awọn ọmọ ti ko niṣẹ naa wa nibẹ, lọdọ tiwọn, ọmọ ti ko ba ni iṣẹ lọwọ rara, ijọba wọn niye ti wọn n ṣeto fun un ti yoo maa na, ti ko fi ni i huwa ti ko dara nigboro. Bakan naa ni ijọba maa n fun wọn ni ounjẹ, oloṣelu kan ko si ni i ko ounjẹ naa pamọ. Ni asiko arun Korona, awọn kan gbe aworan ounjẹ ti wọn fun awọn ara Amuwo-Ọdọfin jade, ṣugbọn to jẹ niṣe ni aṣofin yii ko o pamọ, to waa fi ṣe ẹbun fawọn eeyan lasiko ayẹyẹ ọjọọbi rẹ. Ọrọ ti Mojisọla sọ fi han bii ẹni ti ko mọ ohun to n lọ nipa awọn ọdọ wa, kaka ko si gbẹnu dakẹ, ohun to sọ si wọn ko daa, nitori o ni amugbo ni wọn. Ojuṣe oloṣelu ni lati ṣoju awọn eeyan rẹ, eeyan ko si le jẹ aṣoju awọn eeyan ti ko ba mọ tabi ti ko mọ ohun to n yọ wọn lẹnu. Mojisọla yii ko mọ ohun to n yọ awọn ọdọ lẹnu, ko si yẹ ko wa niru ile-igbimọ to wa yii, awọn to yan an sibẹ ko ṣe daadaa. Ki wọn tete pe e pada, ko loo kọ nipa iwa awọn ọdọ adugbo rẹ ati ti Naijiria, lẹyin naa, ko waa pada wa sileegbimọ aṣofin. Titi igba naa, orukọ ti wọn yoo maa pe e ni Mojisọla alasọjaamu!

 

Ohun to ṣẹlẹ l’Ogbomọṣọ yii ko daa

Nigba ti awọn ti wọn n ṣe iwọde SARS kọ lu aafin Ajagungbade, Ṣọun Ogbomọṣọ lọsẹ to lo lọhun-un, Gomina Ṣeyi Makinde debẹ ba wọn daro, o si ṣe ileri pe ijọba oun yoo fun wọn ni miliọnu lọna ọgọrun-un Naira, ki wọn le fi tun aafin naa ṣe. Gbogbo eeyan lo patẹwọ fun gomina, inu ọba funra rẹ si dun. Ṣugbọn ko ju ọjọ mẹta kan lọ lẹyin ẹ ti iwe kan jade lati aafin ọba yii, nibi ti wọn ti sọ pe Ṣọun loun ko gba owo mọ, oun ko fẹ owo Makinde, ninu ọgọrun-un miliọnu to fẹẹ foun, ko kuku foun ni miliọnu mẹwaa pere, ko fi eyi to ku tun aye awọn ara ipinlẹ Ọyọ ṣe. Dajudaju, bi lẹta naa ti jade, o ti han pe ọwọ awọn oloṣelu wa nibẹ, ati pe wọn fẹẹ fi kinni naa da yẹyẹ gomina wọn silẹ ni. Ko pẹ rara ti eyi fi foju han daadaa, nitori Ṣọun funra ẹ jade, o ni oun ko mọ kinni kan nipa lẹta naa awọn ti wọn fẹẹ da wahala silẹ lo gbe e jade. Ṣugbọn lẹta naa, wọn fi iwe Ọba Ajagungade kọ ọ, wọn si fi orukọ ati adirẹsi aafin rẹ si i. Nidii eyi, o ṣoro ki ẹnikẹni too sọ pe lẹta naa ko wa lati aafin Ṣọun. Ṣugbọn ọba naa ni ki i ṣe ọdọ toun o. Bo ba ri bẹẹ, a jẹ awọn eeyan kan ti wọn n fi eto idagbasoke Ogbomọṣọ ṣe oṣelu ni wọn wa nidii ẹ, eleyii ko si daa. Ko daa nitori pe ki i ṣe gbogbo gomina ni yoo wa si Ogbomọṣọ lati waa fun wọn lowo fi tun aafin ṣe, awọn gomina mi-in n bọ ti wọn ko ni i mọ aafin Ogbomọṣọ, ti ohun yoowu to ba si ṣe wọn nibẹ ko ni i kan wọn rara. Eyi lo ṣe jẹ ohun yoowu ti wọn ba ri lọwọ gomina yii, ki wọn gba a lati tun ibẹ ṣe. Ati pe awọn ti wọn fi ọrọ yii ṣe oṣelu yii gbọdọ mọ pe owo naa ki i ṣe eyi ti wọn fẹẹ ko fun Ṣọun, owo ti wọn fẹẹ fi tun aafin ṣe ni, bi wọn ba si ṣe e daadaa, aafin naa yoo dapewo fun gbogbo aye. Bi wọn ba tun aafin yii ṣe daadaa, ti wọn tun awọn ohun iṣẹnbaye ibẹ ṣe, ki i ṣe Ajagungbade yii nikan ni yoo wa fun, gbogbo ẹni to ba jẹ Ṣọun ni. Ki waa ni wọn yoo fi ẹtanu ati oṣelu ba iru eyi jẹ si. Ohun ti ko dara leleyii, bii igba ti a n di ara ẹni lọwọ ni. Ẹ ma fi oṣelu, tabi ẹtanu, di eto idagbasoke lọwọ nibikibi nilẹ Yoruba, ohun to ṣẹlẹ l’Ogbomọṣọ yii ko daa!

 

Dapọ Abiọdun ṣeun ṣeun

Nibi ti awọn gomina mi-in ṣi ti n pariwo ko ni i ṣee ṣe, awọn o le ṣe e, ati awọn ariwo mi-in bẹẹ, Gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun, ti bẹrẹ si i san owo-oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa o. Awọn ti wọn gba owo tiwọn ni ipari oṣu kẹwaa yii kan ri i pe owo awọn ti le si i ni, ati pe owo oṣu tuntun lawọn gba. Eleyii daa gan-an ni, nitori ko si ẹni to gba a ti ko ni i rẹrin-in, tabi ti inu rẹ ko ni i dun si gomina wọn. Nnkan ti bajẹ ju, ọrọ naa ko si rọrun fun awọn oṣiṣẹ ijọba rara. Ohun to ṣẹlẹ naa ni pe gbogbo ọja lo gbowo lori pata, ko si si ọna mi-in ti wọn yoo fi ṣe aye wọn pẹlu owo-oṣu to kere ti wọn n gba yii, afi ki ijọba funra ẹ ṣe atunṣe si owo wọn. Ohun ti ariwo ṣe wa niluu tẹlẹ ree, ti awọn mi-in si sọ pe awọn ko ni i ṣiṣẹ bi ijọba ko ba sanwo oṣu tuntun fawọn. Awọn gomina mi-in ti gba, awọn mi-in ṣi n ṣe agidi. Ninu awọn ti wọn gba paapaa, wọn ko ti i san an, wọn n fonii donii, fọla dọla ni. Eyi lo ṣe yẹ keeyan gboriyin fun Dapọ Abiọdun nipinlẹ Ogun, ọkan ninu awọn akọkọ gomina ti yoo sanwo oṣu tuntun. Kawọn gomina ilẹ Yoruba to ku pata yaa fara we e o, ki nnkan le daa yikayika fawọn oṣiṣẹ ijọba gbogbo.

Leave a Reply