O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Nibo lawọn eeyan yii wa o

Nigba ti wọn gbe fidio kan jade lọsẹ to kọja yii, ẹni ba ranti ọrọ naa yoo si miri titi. Fidio ohun to ṣẹlẹ lọdun mẹwaa ṣẹyin ni. Lasiko tawọn araalu n fi ibinu han ni, nigba ti awọn oloṣelu fẹẹ doju ijọba Jonathan bolẹ ni tipatipa, ti wọn waa lo awọn ajijagbara lati mu erongba wọn ṣẹ. Nigba ti Ọlọrun yoo mu Jonathan naa, niṣe lo fi owo kun owo epo lojiji lọjo kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 2012, ni epo ba fo lau lati N65, lo ba di N141, fun lita epo bẹntirooolu kan. N lawọn araalu ba yari, bawo lawọn yoo ṣe maa ra epo ni ọkanlelogoje naira, fun kin ni, ati nitori kin ni! Eyi lawọn oloṣelu igba naa mu lọwọ, ni wọn ba dẹ awọn ajijagbara sijọba yii. Kia ni iparojọ nla kan ti ṣẹlẹ ni Ọjọta, l’Ekoo,*** nibi ti ẹgbẹ kan ti Pasitọ Tunde Bakare, Save Nigeria Group, ti ko ọpọlọpọ ero jọ, ti kaluku n sọrọ pe afi ki ijọba da owo epo bẹntiroolu yii pada. Oloṣelu wo ni ko debẹ sọrọ, bẹẹ ni wọn n fi owo ranṣẹ, bẹẹ ni wọn n fi ounjẹ ranṣẹ, bẹẹ ni awọn akọrin ati onitiata n wa, bẹẹ ni mọto ko ṣiṣẹ, ti ko si ṣẹni to le lọ sibi kan fun bii ọjọ mẹta. Nigba ti ọrọ naa le gan-an, ijọba ko le ṣe ohun meji, wọn da owo epo naa pada si naira mẹtadinlọgọrun-un (N97) kiakia, nigba ti nnkan si tun dara, wọn da a pada si naira metadinlaaadọrun-un. Bẹẹ lawọn eeyan yii gba araalu silẹ nigba naa, wọn si ko wa yọ ninu ewu ati ijọba pakaleke. Ṣugbọn ijọba Buhari to ba owo epo ni N87 ti ṣe kẹrẹkẹrẹ sọ owo epo naa di aadọjọ naira (N150) bayii, bo si tilẹ jẹ pe asiko inira lo bọ si faraalu, ko sẹni kan ti wọn ri ti yoo dide ja fun wọn. Ki lo de? Nibo lawọn eeyan ti wọn ja ija yii nijọsi wa? Awọn eeyan ti wọn ja nijọsi yii kuku wa laye, wọn ko lọ sibi kan, koda, wọn wa laarin wa ti ohun gbogbo yii si n ṣẹlẹ loju wọn. Iyatọ to kan wa nibẹ ni pe awọn ni wọn n ṣejọba bayii, wọn ko si le jade ki wọn sọ faraalu pe ohun ti awọn n ṣe ko dara. Tunde Bakare to ṣaaju ikede ọjọ naa, ọrẹ timọtimọ lo jẹ fun Buhari, ko si si ohun ti Buhari ṣe loju rẹ ti ko ni i jẹ daradara ni. Bẹẹ naa lo jẹ pe awọn oloṣelu ti wọn pọ ninu awọn iwọde naa ju lọ, wọn ti wa ninu APC bayii, awọn ni aṣaaju ẹgbẹ yii, wọn ko si le gba ki ẹnikẹni ṣe iru iwọde ti wọn ṣe lọjọ naa lasiko yii rara. Ohun ti a si n wi niyẹn. Ibajẹ ko lorukọ meji, ibajẹ ni. Bi eeyan kan ba si n gbogun tiwa ibajẹ, ni gbogbo ibi to ba ti ri i lo yẹ ko ti gbogun ti i. Ki i ṣe ka gbogun tiwa ibajẹ loni-in, nitori pe awọn ọta wa lo n ṣe e, bo ba di asiko ti awọn ọrẹ wa, ka yiju si ẹgbẹ kan. Ohun ti awọn eeyan yii n ṣe ree, sibẹ, wọn yoo maa beere ẹsan iwa rere lọdọ Ọlọrun. Ọlọrun ki i ṣe alaboosi, yoo fun kaluku ni ẹsan to ba tọ si i.   

 

 Ẹ ṣa ma tun ko wa si wahala tuntun

Wahala tuntun mi-in lo tun n bọ yii, ijọba si gbọdọ tete yaa ri i pe awọn pana ẹ, ko too tun di ohun ti yoo ko ara ilu siyọnu, paapaa ni ilẹ Yoruba wa nibi o. Awọn tanka ti wọn n gbe epo ni wọn ni awọn yoo da iṣẹ silẹ, wọn ni awọn ko ni i lọọ gbe epo lati dẹpo epo l’Ekoo, wọn tilẹ ni tirela elepo kankan ko ni i wọ ilu Eko wa ni. Ohun ti eleyii n mu bọ ni idaamu fawọn eeyan, nitori laipẹ lai jinna, bi iru eleyii ba fi ṣẹlẹ, epo bẹntiroolu yoo di ọwọngogo, lẹsẹkẹsẹ ni wahala tuntun yoo si bẹrẹ fawọn eeyan kaakiri. Bi wọn ko ba ti gbe epo ni Eko, yoo kan ara Ibadan, yoo de Ado-Ekiti pẹlu Ondo, gbogbo ara Ọṣun, Ijẹbu ati Abẹokuta ni yoo si mọ pe nnkan ṣẹlẹ, nitori gbogbo ibi yii ni epo ti wọn n gbe lati Eko n lọ ju lọ. Ko si ohun ti awọn eeyan yii ni awọn ko ni i tori ẹ gbe tanka epo awọn jade ju ọrọ awọn agbofinro ti wọn n yọ wọn lẹnu lọ. Wọn ni nigba yoowu ti tanka epo yoo ba jade kuro l’Ekoo, tabi ti yoo ba wọ ilu Eko, awọn ọlọpaa, ṣọja ati awọn mi-in ti wọn ko si ibi Ọja Kara yoo da awọn duro, wọn ko si ni i jẹ ki awọn lọ, afi ti wọn ba gba owo to to owo lọwọ awọn. Bi awakọ kan ba ṣe agidi pe oun o ni i sanwo yii, wọn yoo fo sori mọto rẹ, wọn yoo yọ mirọ, iyẹn gilaasi to fi n riran, tabi ki wọn lu gilaasi to wa niwaju mọto fọ pata. Gbogbo iwa ika yii ni awọn onitanka naa ni awọn ko ni i tori rẹ lọọ gbe epo mọ, nitori gbogbo igba lawọn ti fẹjọ sun awọn ti wọn n ṣejọba, sibẹ wọn ko ba awọn ṣe kinni kan si i. Lara ijakulẹ ijọba to wa lode yii ree. Bawo ni ijọba yoo ṣe ni ọlọpaa tabi awọn ṣọja ti ẹnu wọn ko ni i ka wọn. Olori ọlọpaa ti paṣẹ titi pe awọn ọlọpaa ko gbọdọ duro loju titi gba owo lọwọ ẹnikẹni, koda, wọn ko gbọdọ da ọlọkọ kankan duro. Ṣugbọn awọn eeyan naa ko kuro loju ọna, wọn wa nibẹ lojoojumọ pẹlu ibọn. Araalu wo ni yoo waa maa ba wọn lo agidi, nigba ti iroyin iku ojiji kun ilu lori awọn ti wọn ba ọlọpaa oju ọna ṣagidi, ti wọn yinbọn pa. Awọn ọlọpaa yii a maa paayan nitori ọgọrun-un naira pere, ṣe iyẹn leeyan yoo waa duro ti ko ni i tete yaa ṣe ohun ti wọn ba ni ko ṣe. Ijọba to ko wọn sọna lo le gba araalu, awọn olori ọlọpaa naa ni wọn le gba awọn eeyan yii lọọ awọn ole ati igaara ọlọṣa ti wọn n pe ara wọn ni ọlọpaa yii. Iṣoro to wa nibẹ ni pe ọpọ ọga ọlọpaa ti wọn wa ni tesan ni wọn n gbowo lọwọ awọn ti wọn ba ran jade. Nibi yii lọrọ ti kan ijọba, ijọba ni yoo gba awọn eeyan ilu, nipa riri i pe wọn ko awọn ọlọpaa afibọn-gba-riba yii kuro lọna, ti wọn si le awọn ọga wọn to n ran wọn jade lati da araalu lọna yii kuro lẹnu iṣẹ ọba. Ṣugbọn ẹ tiẹ kọkọ yanju eleyii na, ẹ tete ba awọn onitanka yii sọrọ, ẹ fi wọn lọkan balẹ, ki ẹ si ko awọn ọlọpaa ole yii kuro ni popo. Asiko Korona yii kọ lo tun yẹ ki epo mọto wọn o. Ẹ ma fiya jẹ wa pa!

 

Ki Mimiko ṣọra ẹ lẹyin Agboọla

Iroyin to n jade kaakiri ipinlẹ Ondo, to tun n lọ kiri ilẹ Yoruba bayii ni pe Dokita Oluṣẹgun Mimiko to fọdun mẹjọ ṣe gomina ipinlẹ Ondo, to ṣe minisita, to si ṣe akọwe ijọba, lo wa lẹyin Agboọla Ajayi, Igbakeji gomina ipinlẹ naa, ẹni to sa kuro ninu ẹgbẹ oṣelu ti oun ati ọga rẹ jọ n ṣe, to sa lọ sinu egbẹ PDP, nigba ti ko si ri ohun to n wa ninu PDP, to sa wa sinu ẹgbẹ ZLP, ẹgbẹ ti Mimiko. Arun kan naa lo maa n ba awọn oloṣelu ja, iyẹn naa ni pe wọn ki i mọ bi agbara wọn ti to. Eyi ti agbara rẹ ko to nnkan yoo maa sọ pe oun le sọ oke dilẹ, oun le sọ apata nla di ilẹ gbẹrẹfu, o digba to ba ṣẹlẹ ko too ri i pe gbẹrẹfu lasan loun. Ninu awọn gomina to ti jẹ sẹyin, ipo apọnle kan ni Mimiko wa, ohun to si fi i si ipo apọnle yii ni ọwọ ati ọla ti ẹni to wa nipo naa bayii, iyẹn Akeredolu, n bu fun un. Bi Mimiko ba waa yipada, to n lẹdi apo pọ mọ alatako Akeredolu, oun naa yoo di ọkan ninu awọn alatako gomina naa ree, alatako ẹni ko si le ro rere si ni, bi oun ko ba si ti ro daadaa si Akeredolu, Akeredolu naa lẹtọọ lati ma ro daadaa si i. Itumọ eyi ni pe gbogbo aṣiri Mimiko ti wọn de mọlẹ tẹlẹ ni yoo bẹrẹ si i tu sita. Eleyii ko ni i daa fun gomina atijọ naa, ṣugbọn ko sẹni ti yoo ba a kẹdun, oun lo fori ara ẹ fa gọgọ, ohun to ba si ja le e lori, ko fara mọ ọn ni.

 

Ati Ali Ọlanusi, ati Agboọla, ẹgbe ẹyẹ lẹyẹ i wọ tọ

Ilu yii, ati orilẹ-ede yii, ni ọpọ eeyan wa nigba ti Alaaji Ali Ọlanusi kuro lẹyin Oluṣẹgun Miniko, to lọọ ṣiṣẹ pẹlu awọn ọta rẹ, to ni gomina naa ko fun oun ni ẹtọ oun. Ohun ti oun ṣe lọjọ naa ni Agboọla Ajayi to jẹ Igbakeji gomina bayii naa fẹẹ ṣe. Bi a ba fẹ ilọsiwaju lorilẹ-ede yii, paapaa ni ilẹ Yoruba tiwa, a ko gbọdọ gba awọn oloṣelu yii laaye ki wọn maa gba araalu sibi ti wọn ba ti fẹ, tabi ki wọn maa pe awọn eeyan wa lọbọ. Agboọla ni ọga oun ṣẹ oun ni, kaka ko duro ninu APC ti wọn jọ wa ki wọn yanju ọrọ, o fi ibẹ silẹ, o sare gba inu PDP lọ. O ti ro pe wọn yoo fi oun ṣe oludije gomina, ṣugbọn awọn ti wọn ti n jiya ẹgbẹ bọ lati bii ọdun mẹwaa tabi ju bẹẹ lọ sẹyin ko gba, wọn ni ko le waa ko ire nibi ti ko roko si. N lo ba tun sare jade nibẹ, o  wa inu ẹgbẹ mi-in lati lọ. O ṣaa fẹẹ ṣe gomina yii ni gbogbo ọna. Ṣugbọn kin ni iru ẹni bayii yoo ṣe faraalu to ba di gomina to n le kiri yii, ẹni to jẹ iwọra ati wọbia lasan lo n ti i kiri, ti ki i ṣe ifẹ araalu. Tabi ẹ ti ri ẹni to fẹran aarala ti yoo maa rin irin are bayii kiri bi! Ti Agboọla ko waa ni i jọ ni loju mọ bi eeyan ba ri ti Alli Ọlanusi, ẹni to ba Mimiko ja nigba to n ṣe gomina pe oun ko ri ẹtọ gba, ṣe asiko ti Mimiko ko ṣe gomina mọ yii ni yoo waa ri ẹtọ gba. Bẹẹ kọ, nitori Agboọla loun naa ṣe n rin kiri, ki Agboọla wọle, ki gbogbo agbara ipinlẹ Ondo bọ si wọn lọwọ, ki owo ipinlẹ Ondo wa larọọwọto wọn, ki wọn si maa ṣe yalayolo bo ba ṣe wu wọn ni. Ohun ti baba arugbo yii n le kiri ree, oju si gbaayan ti, pe iru baba ni yoo wa nidii awọn nnkan bẹẹ yẹn. Bi Akeredolu ṣe e daadaa, bi ko ṣe e daadaa, awọn eeyan Ondo ki i ṣe ọdẹ, awọn ni wọn yoo fi ibo wọn fun un lesi idanwo to ba ṣe. Ṣugbọn ki i ṣe ki awọn ọjelu kan maa rin kiri lati fi juujuu bo araalu loju, iwa ika ni, Ọlọrun ko si fẹ ẹ. Koda, Odua naa ko fẹ ẹ!

 

Ni ti iku Buruji Kasamu ati ọrọ Ọbasanjọ

Nigba ti ariwo iku Ẹṣọ Jinadu (Buruji Kaṣamu) jade sita, awọn eeyan n pariwo lọtun-un losi, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ si waa sọrọ kan. O ni Kasamu lo gbogbo ọgbọn ati ete lati ge awọn agbofinro ti wọn fẹẹ mu un fun iwa ọdaran ni Naijiria ati lẹyin odi legee iwọsi, o ge wọn titi ti wọn ko fi ri i mu, ṣugbọn ko le ge Ọlọrun legee, lọjọ ti iku de naa ni iku mu un lọ. Awọn eeyan ro pe eebu lọrọ naa, o si dun awọn mi-in pe Ọbasanjọ n sọrọ si oku ọrun. Ṣugbọn ko si ohun ti eeyan yoo ṣe laye ti ko ni i ditan, nigba ti ẹda ba ku naa, dandan ni ki wọn ranti ohun to ba ṣe. Ati pe ilu bẹmbẹ nile aye, bo ba kọju si ẹni kan, ẹyi ni yoo kọ si ẹlomiiran. Bi Buruji ba ṣe daadaa loju awọn kan, awọn mi-in mọ ọn deledele, ti wọn si mọ pe ko ṣe daadaa. Ṣugbon pataki to wa nibẹ ni pe ẹkọ gidi lo yẹ ki iku Kasamu yii jẹ fawọn oloṣelu, iyẹn awọn ti wọn ba ni laakaye ninu wọn. Tabi ọjọ wo ni Kaṣamu n ja fun akoso PDP l’Ogun, ọjọ wo nibi na! Ọjọ wo lo n ja lori ọrọ ileeṣẹ onitẹtẹ ti wọn jọ n ṣe. Ọjọ wo ni na! Ọjọ wo nibi naa lawọn aye n pariwo Buruji Kaṣamu pẹlu owo to ni, ọjọ wo nibi na! Ṣugbọn Buruji Kaṣamu da loni-in, ẹran ti lọ! Koda, beeyan n gun ẹṣin, ko le ba a mọ. Bi yoo si ti ṣẹlẹ si gbogbo ẹda aye niyẹn. Afi awọn oloṣelu ti ki i ṣe laakaye, ti wọn yoo ro pe aye yii ni wọn yoo ju si, pe ẹni to ku yẹn ko mọ ọn ṣe ni. Ẹ wo o, ẹ jẹ yaa ṣe rere, nitori ko si ibi ti ẹ oo gbe e gba, iku to pa Kaṣamu ọrẹ yii yii naa yoo pa yin dandan!

Leave a Reply