O ṣẹlẹ, adajọ ju ọmọ ẹgbẹ fijilante sẹwọn n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin to ṣẹṣẹ pari yii ni adajọ ju afurasi ọdaran kan to jẹ ọmọ ẹgbẹ fijilante, Tunde Arọni, ẹni ọdun marundinlọgbọn, sọgba ẹwọn Òkè-Kúrá, niluu Ilọrin, titi ti igbẹjọ yoo fi waye lori ẹsun gbigbe ohun ija oloro kiri lọna aitọ ti wọn fi kan an.

Ileeṣẹ ọlọpaa lo wọ afurasi, to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ fijilante ọhun lọ sile-ẹjọ fẹsun pe o gbe awọn ohun ija oloro kiri lọna aitọ. Wọn ni agbegbe Ìta-Àmọ́dù, niluu Ilọrin, lọwọ ti tẹ ẹ, nibi to fara pamọ si. Lara awọn ohun ija oloro ti wọn ba lọwọ rẹ ni ibọn agbelẹrọ kan ati aake kan.

Agbefọba, Yakubu, sọ fun kootu pe lẹyin ti awọn olugbe agbegbe naa ta ọlọpaa lolobo pe awọn afurasi ọdaran kan n farapamọ ṣiṣẹ buruku nibẹ ni awọn ẹsọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n ri si ẹsun idigunjale lọ si agbegbe naa, tọwọ wọn si tẹ Tunde Arọni, pẹlu awọn ohun ija oloro lọwọ rẹ, ti ko si le ṣalaye lori bi awọn nnkan naa ṣe jẹ.

Nigba ti wọn bi afurasi naa boya o jẹbi tabi ko jẹbi, o loun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Yakub rọ ile-ẹjọ ko fi afurasi naa si ahamọ titi ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun ọdaran ti wọn fi kan an, o ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n tẹsiwaju lori iwadii wọn.

Agbẹjọro olujẹjọ, Amofin Toyin Ọnaọlapọ, rọ adajọ ko gba beeli onibaara rẹ, o ni ko le sa lọ, yoo maa fara han nile-ẹjọ nigbakuugba ti kootu ba fẹ.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, onidaajọ Bamgbọla pasẹ pe ki wọn sọ afurasi naa sọgba ẹwọn Òkè -Kúrá, o sun igbẹjọ si ọjọ miiran ọjọ ire.

Leave a Reply