Ọwọ ọlọpaa ti tẹ mẹta ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n da omi alaafia ilu ru ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni ọwọ ileesẹ ọlọpaa Kwara, tẹ mẹta ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn da rogbodiyan silẹ niluu Ẹyẹńkọrin, Bùdó-Òkè, nijọba ibilẹ Aṣà, nipinlẹ naa, nibi ti wọn ti dana sun ile meji, ti wọn si ṣeku pa ọkan lara wọn, iyẹn Adams Isah, ẹni ọdun mejidinlogun, to tun jẹ nọmba waanu ninu ọmọ ẹgbẹ okunkun niluu ọhun.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, ASP Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, lo ti ṣalaye pe ija lo sadeede bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji kan, Adams Isah ati Rasaq Ọlọrunwa, ti Rasaq si gun Adams lọbẹ laya, niyẹn ba ku patapata, eyi lo mu ki rogbodiyan bẹ silẹ lawọn ilu mejeeji ọhun.

O tẹsiwaju pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ mẹta lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun. Orukọ wọn ni Suleiman Ismail, Mahmud Ibrahim ati Mudashir Saheed, ti wọn n yinbọn lasiko ti rogbodiyan naa n lọ lọwọ. O ni awọn agbofinro ṣi n wa Rasaq Ọlọrunwa, to ṣeku pa Adams bayii.

Kọmisanna ọlọpaa ni Kwara, CP Victor Ọlaiya, ni iwa ọdaran paraku ni ṣiṣe ẹgbẹ okunkun ninu iwe ofin ilẹ wa, o waa kilọ fun gbogbo awọn ọdọ lati jinna si i, bakan naa lo ni ohun gbogbo ti pada sipo niluu Ẹyẹńkọrin bayii, alaafia ti jọba.

Tẹ o ba gbagbe, lati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin yii, ni ibẹru-bojo ti gbilẹ lawọn agbegbe kan niluu Ẹyẹńkọrin, Bùdó-Òkè ati Bàllàh, nijọba ibilẹ Aṣà, nipinlẹ Kwara, latari bi awọn ọmọ ẹgbẹ kunkun ṣe n rẹ ara wọn danu bii ila, ti wọn si n da awọn araadugbo laamu. Wọn pada ṣeku pa ọkan ninu wọn laaarọ kutukutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ti wọn si tun dana sunle.

Leave a Reply