O ṣẹlẹ, ijọba ti mu Gumi, wọn ni ko waa sọ tẹnu ẹ lọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ

Faith Adebọla

Ijọba apapọ orileede yii ti ke si gbajugbaja olukọ ẹsin Islam lapa Oke-Ọya, to tun maa n ṣe wọlewọde pẹlu awọn janduku agbebọn nni, Sheikh Abubakar Ahmad Gumi, pe ko tara ṣaṣa yọju si awọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ l’Abuja, tori wọn ni awọn ibeere kan ti wọn fẹẹ beere lọwọ ẹ lori awọn ọrọ ti wọn lo jade lẹnu rẹ lẹnu ọjọ mẹta yii. Wọn lọrọ rẹ gba ifura, o si gbọdọ ṣalaye fawọn agbofinro, Gumi si ti wa lakata wọn bayii.

Minisita feto iroyin nilẹ wa, Mohammed Idris, lo sọrọ yii di mimọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ laṣaalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, nile ijọba to wa l’Abuja.

Ẹ oo ranti pe laipẹ yii Gumi ju’ko ọrọ sijọba apapọ atawọn agbofinro latari bi wọn ṣe fi awọn orukọ kan lede pe awọn eeyan ọhun lawọn fura si pe wọn n ṣatilẹyin fawọn afẹmiṣofo, ti wọn si n ṣe agbodegba fawọn janduku agbebọn atawọn ajinigbe kaakiri orileede yii. Gumi ni bijọba ṣe kede awọn orukọ wọnyi lodi, ati pe ijọba ko laṣẹ lati ṣe bẹẹ rara, o ni ile-ẹjọ nikan lo laṣẹ labẹ ofin lati kede orukọ ẹnikẹni tabi ẹgbẹ kan gẹgẹ bii alatilẹyin awọn ọbayejẹ, ọkunrin naa ni iwa ibanilorukọjẹ ati ifabuku-kan-ni nijọba apapọ hu, ohun to si le la wahala lọ labẹ ofin ni pẹlu.

O tun sọ pe oun ko lodi si ki eyikeyii tabi ẹnikẹni ti wọn ba fidi ẹ mulẹ pe o ṣatilẹyin fawọn afẹmiṣofo jiya to tọ si i labẹ ofin, amọ ohun toun n sọ ni pe ile-ẹjọ nikan lo le kede irufẹ awọn ẹni bẹẹ, to si le fiya jẹ wọn, ki i ṣe ijọba apapọ tabi awọn agbofinro rẹ.

Nigba to n sọrọ lori ohun ti Gumi sọ yii, Minisita Idris sọ pe:

“Ko si ohunkohun to le di ijọba lọwọ lati wadii ohunkohun to ba ti maa ran wa lọwọ lati yanju iṣoro wa. Awọn ẹṣọ alaabo gbogbo ti n ṣe ojuṣe wọn nipa ẹ.

“Sheik Gumi, tabi ẹnikẹni yoowu ti ibaa jẹ ko ga kọja ofin, to ba ni amọran kan to le ṣeranwọ, to si le wulo fawọn agbofinro lẹnu iṣẹ wọn, a fẹẹ gbọ amọran naa, a maa gba a wọle.

“Amọ ti wọn ba fura pe iṣọwọ sọrọ rẹ ti di ti ẹnu-n-ja-waya, to ti fẹẹ di asọrọ-yaa bii ẹni da omi sinu agbada, wọn yoo da sẹria gidi fun un. Ko sẹnikẹni to ga ju ofin lọ. Ẹ jẹ ki n daale nibẹ. Mo si mọ pe ba a ṣe n sọ yii, awọn ẹṣọ alaabo ti gba a lalejo lati dahun awọn ibeere kan, o ti wa lakata wọn.

“Teeyan ba sọrọ, paapaa tọrọ naa ba jẹ mọ ti eto aabo gbogbo ilu, ojuṣe awọn ẹṣọ alaabo apapọ ni lati yiri ọrọ ẹni naa wo finnifinni, ki wọn si ṣakiyesi ẹ daadaa, ohun ti wọn n ṣe lọwọlọwọ niyẹn, tori ko sẹni to ga kọja ofin,” gẹgẹ bi minisita naa ṣe wi.

Leave a Reply