Ijọba ko san kọbọ fawọn ajinigbe ti wọn fi tu awọn akẹkọọ Kaduna silẹ – Minisita eto ẹkọ

Faith Adebọla

Minisita feto ẹkọ nilẹ wa, Ọjọgbọn Tahir Mamman, ti sọ pe lọfẹẹ-lofo lawọn ajinigbe yọnda awọn ogowẹẹrẹ bii ọọdunrun ti wọn ji gbe nileewe LEA Primary School and Government Secondary School, to wa niluu Kuriga, nijọba ibilẹ Chikun, nipinlẹ Kaduna. O ni ijọba ko san kọbọ lati gba ominira fawọn ọmọleewe naa rara.

Ọjọgbọn Mamman sọrọ yii lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, nibi eto idanilẹkọọ ọlọjọ meji kan ti wọn ṣe fawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ eto ẹkọ l’Abuja, eyi to bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde, naa.

Lẹyin to ti kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi olukọ ileewe kan to ku sakata awọn ajinigbe, o ba awọn mọlẹbi atawọn majeṣin ti wọn lo ọsẹ meji aabọ lakata awọn ajinigbe ọhun, amọ ti wọn mori dele yọ. Minisita si gboṣuba nla fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu atawọn agbofinro gbogbo fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati ri i pe awọn igbekun rẹpẹtẹ naa dẹni ominira nigbẹyin, ti wọn si ṣe bẹẹ lai san owo itusilẹ fawọn ajinigbe naa.

Bakan naa lo sọrọ lori eto idanilẹkọọ tuntun ati iṣẹ tileeṣẹ eto ẹkọ fẹẹ gun le bayii, o ni: “A ti bẹrẹ iṣẹ bayii lati ni akọsilẹ to peye nipa awọn ileewe wa. A gbọdọ mọ gbogbo akẹkọọ kọọkan ati tiṣa kọọkan nileewe kọọkan ni Naijiria, nitori ko si iru akọsilẹ bẹẹ latigba pipẹ sẹyin. A gbọdọ lakọọlẹ bi awọn ẹkọ ṣe n lọ si lawọn ileewe, adirẹsi ileewe kọọkan, awọn irinṣẹ ati nnkan eelo to wa nibẹ, bawo lawọn akẹkọọ-kunrin ṣe pọ to ni ifiwera si akẹkọọ-binrin, awọn ọmọ meloo ni wọn n sa nileewe, awọn meloo ni wọn n ri ileewe wọ, ipo wo si lawọn ileewe wọnyi wa.

“Eyi ni yoo mu kijọba le ṣeto ati ofin to maa wulo, ti yoo si fẹsẹ rinlẹ daadaa, ati pe yoo ṣee ṣe lati maa mọ bi nnkan ti n lọ si lawọn ileewe wa gbogbo.”

Ọrọ ti Minisita yii sọ ko yatọ si eyi ti Minisita fun eto iroyin, Mohammed Idris, naa sọ laṣaalẹ ọjọ Aje yii kan naa, nibi to ti fidi ẹ mulẹ pe awọn ko sanwo fun idande wọn.

Leave a Reply