Iya Mohbad tu aṣiri mi-in nipa iku ọmọ ẹ

Faith Adebọla

Abilekọ Abọsẹde Alọba, ti i ṣe iya gbajugbaja onkọrin hipọọpu nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan mọ si Mohbad, ti tu awọn aṣiri kan nipa iku ọmọ rẹ, o ni ooyẹ ni wọn sin ọmọkunrin ọhun, tori ọmọ naa ko ti i ku patapata ti baba rẹ, Alagba Joseph Alọba, fi lọọ sinku rẹ lọdun to kọja.

Obinrin naa ni o ṣi jẹ nnkan iyalẹnu f’oun pe lati bii ọjọ mẹwaa ṣaaju iku rẹ loun ti wa lọdọ ọmọ oun, tawọn si jọ n gbe inu ile kan naa, sibẹ oun ko mọ ohunkohun lọjọ ti wọn ni Mohbad ku, inu okunkun iku rẹ ni wọn fi oun si, oun ọrọ si ti bọ sori k’oun too gbọ nipa gbogbo iṣẹlẹ ọhun.

Mama naa sọ pe: “Mi o mọ kinni kan nipa igba tọmọ mi, Mohbad, ku. Baba wọn ko sọ nnkan kan fun mi. Ṣaaju iku rẹ, ile ẹ ni mo ti wa fun bii ọjọ mẹwaa. Mo sare pada lọ sibẹ ni nigba ti mo gbọ pe o ku. Emi ni mo pe baba ẹ atawọn aburo ẹ lati tufọ fun wọn. Emi ni mo ko wọn jọ.

“Mo pe baba wọn pe ko yọju si mi, mi o tiẹ ro ti gbogbo aburu to ti ṣe si mi latẹyinwa, tori mo mọ pe mi o lagbara lati ba a ja, ati pe awọn ọmọ mi n dun mi ninu ni temi, ọwọ gbogbo wọn ti to eti, wọn ti dagba, mo si n ko gbogbo wọn pọ ni. Amọ niṣe ni baba wọn n da iyapa silẹ laarin wa.

“Mo gbagbọ pe ọmọ mi o ti i ku nigba ti wọn sin in yẹn. Mo ranti pe mo diidi sọ fun wọn pe ki wọn ma ti i sin in, amọ wọn ta ku. To ba jẹ pe wọn o sin in lasiko ti wọn sin in yẹn ni, mo gbagbọ pe ọmọ mi iba ṣi wa laye. Joseph, Baba Mohbad, gan-an ni wahala mi. Mo gbagbọ pe niṣe lo sin ọmọ mi looyẹ, lai ti i ku,” gẹgẹ bii mama naa ṣe sọ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu iweeroyin Punch laipẹ yii.

Ẹ oo ranti pe ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023, ni ọdọmọde olorin taka-sufee naa ku nile rẹ, lagbegbe Lẹkki, nipinlẹ Eko, lẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27).

Ọpọlọpọ awuyewuye lo gbode lasiko naa, latari bi awọn ololufẹ olorin naa atawọn ajafẹtọọ-ọmọniyan ṣe pe fun iwadii ohun to ṣokunfa iku rẹ, wọn ni afaimọ ni ejo ọrọ naa ko lọwọ ninu.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa lọọ hu oku naa lẹyin ọjọ kẹfa, ti wọn si bẹrẹ iwadii ijinlẹ, amọ abajade iwadii naa ko ti i jade, wọn si ti fun awọn afurasi bii Naira Marley, Sam Larry, Primeboy, ti wọn mu lori iṣẹlẹ ọhun ni beeli.

Amọ oriṣiiriṣii ọrọ lawọn eeyan fi fesi lori ẹsun ti Iya Mohbad fi kan ọkọ rẹ yii. Ọpọ eeyan lo bẹnu atẹ lu obinrin naa pe kikuro to kuro nile ọkọ rẹ ni ko jẹ ko le mojuto awọn ọmọ t’Ọlọrun fi jinki rẹ. Bẹẹ lawọn mi-in ba a daro, wọn ni ko gbagbe ohun to ti ṣẹlẹ, tori arokan ni i mu ẹkun asun-i-da wa.

Leave a Reply