O ma ṣe o, ina jo akẹkọọ ileewe fasiti meji pa

Adewale Adeoye

Beeyan ba jori ahun, to ba ri bi ina ṣe jo meji lara awọn akẹkọọ ileewe fasiti ijọba apapọ, ‘Federal University’, to wa lagbegbe Gashua, nijọba ibilẹ Bade, nipinlẹ Yobe, pa, onitọhun aa bomi loju gidi ni. Iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun waye lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni nnkan bii aago kan oru.

ALAROYE gbọ pe inu ọkan lara awọn yara tawọn akẹkọọ obinrin ileewe ọhun n gbe ni ina ọhun ti kọkọ ṣẹ yọ, kawọn alaṣẹ ileewe ọhun si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ina ọhun ti fẹju kọja afẹnusọ.

Lara awọn to pade iku ojiji lasiko ijamba ina ọhun ni awọn akẹkọọ ileewe fasiti meji kan ti wọn wa ni ipele ọlọdun kẹta.

Alukoro ileeṣẹ panapana agbegbe naa, Ọgbẹni Mohammed Goje, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe lojiji lawọn gba ipe pajawiri lati ọdọ awọn alaṣẹ ileewe ọhun pe ina nla ṣẹ yọ ninu yara ileewe awọn akẹkọọ naa.

Ọgbẹni Goje ni, ‘Lojiji ni ina kan ṣẹ yọ ninu yara ileewe awọn akẹkọọ ileewe naa, kawọn akẹkọọ ọhun si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, o ti ka awọn akẹkọọ kan mọ’nu ile ti wọn n gbe. Awọn akẹkọọ ileewe fasiti meji ni wọn ku sinu ijamba ina ọhun, awọn kọọkan fara pa yannayanna lasiko laṣiigbo naa, ti wọn si ti n gba itọju lọwọ nileewosan ijọba kan to sun mọ ileewe ọhun, nigba tawọn to ku ninu iṣẹlẹ ọhun wa ni mọṣuari ileewosan to wa lagbegbe Gashua.

Ọgbẹni Goje ni iwadii nipa ohun to fa ijamba ina ọhun ṣi n lọ lọwọ, kawọn le dena iru iṣẹlẹ ọhun lọjọ iwaju.

Bẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii oṣu kan sẹyin bayii ni ọkan lara awọn ileewe fasiti kan to wa lagbegbe Damaturu, gbana lojiji, tawọn akẹkọọ kan si ku ninu iṣẹlẹ ọhun, nigba tawọn bii meloo kan fara pa yannayanna.

Leave a Reply