O ma ṣe o! Nibi tọkunrin oloṣelu yii ti n kirun lawọn agbebọn pa a si

Monisọla Saka

Ọkunrin oloṣelu kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Alaaji Lado, ti ki aye pe o digbooṣe, lẹyin tawọn agbebọn kan ya wọ abule Mairuwa, nijọba ibilẹ Faskari, nipinlẹ Katsina, lasiko ti wọn n kirun alẹ lọwọ.

Lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, lawọn ọdaju ẹda yii ṣoro, niṣe ni wọn ya wọ’nu mọṣalaṣi lasiko tawọn araalu n kirun alẹ lọwọ, bẹẹ ni wọn doju ibọn kọ ọkunrin oloṣelu yii, ti wọn pa a. Lẹyin ti wọn pa a tan ni wọn tun gbe iyawo atawọn ọmọ ẹ obinrin meji lọ.

Ẹlomi-in toun naa tun kagbako iku ninu iṣẹlẹ laabi yii ni ọkunrin ti wọn n pe orukọ ẹ ni Sani, to jẹ oṣiṣẹ eleto ilera, Mairuwa Health Facility, to wa ni abule naa.

Wọn ni awọn agbebọn naa ko ti i pe ẹnikẹni ninu ilu nipa bi wọn yoo ṣe ṣeto itusilẹ awọn ti wọn ji gbe lọ ati iye ti wọn fẹẹ gba.

Iwa ijinigbe yii ti di lemọlemọ bayii, paapaa lagbegbe Oke-Ọya. Laipẹ yii ni wọn ji awọn eeyan kan nipinlẹ Kaduna, ti awọn agbebọn naa si n beere fun biliọnu kan Naira. Bakan naa ni wọn ya bo ọja kan lasiko tawọn araalu naa n naja naa lọwọ nipinlẹ Niger, lọsẹ to kọja yii. Wọn pa olori ilu kan nibẹ, wọn si jiawọn eeyan mi-in gbe lọ. Ọpọ lo si fara pa lasiko ti wọn n gbiyanju lati sa asala fun ẹmi wọn, ti wọn si wa nileewosan bayii.

Leave a Reply