Nitori Yusuf tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun pa n’Ilọrin, rogbodiyan nla ṣẹlẹ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

 Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Abiọdun, to n gbe ni agboole Ghana (Ghana house), sẹku pa gende kan torukọ rẹ n jẹ Yusuf, ti wọn ni o ṣẹṣẹ ṣegbeyawo laipẹ yii, ti iyawo rẹ si ti wa ninu oyun lagbegbe Pàkákà, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara. Lẹyin to pa a tan lo sa lọ. Iṣẹlẹ yii si ti fa rogbodiyan nal sagbegbe naa, nibi ti ọpọ eeyan ti fara pa, bẹẹ ni ọpọ dukia tun ṣegbe.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, laaarọ kutukutu ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta yii, ni awọn ikọ Yusuf ti wọn pa ya bo agboole awọn Abiọdun, ti wọn n pe ni (Ghana house), lagbegbe Pàkátà, wọn bẹrẹ si i yinbọn, ti gbogbo awọn olugbe agbegbe naa si bẹrẹ si i sa asala fun ẹmi wọn. Ẹni duro gbe, ẹni bẹrẹ daran, ti gbogbo agbegbe si da paroparo. Awọn ọmọ janduku yii wọ agboole Ghana lọ, wọn si n ṣa gbogbo awọn ti wọn ri ladaa, ọpọ lo fara gbọgbẹ, bakan naa ni wọn ba ọpọlọpọ dukia jẹ.

Nigba ti iroyin tẹ awọn ọlọpaa lọwọ ni wọn lọ si agbegbe naa, ti wọn si lọọ pana rogbodiyan ọhun, gbogbo awọn ọmọ janduku naa sa lọ patapata, ṣugbọn awọn iya agbalagba to jẹ mọlẹbi Abiọdun ni awọn ọlọpaa ko lọ satimọle.

Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun akọroyin ALAROYE, o ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply