Ọpẹ o, wọn ti tu awọn akẹkọọ tawọn agbebọn ji gbe ni Kaduna silẹ

Faith Adebọla

Orin, ‘aja to re’le ẹkun to bọ, o tọpẹ’, lo gba ẹnu mọlẹbi awọn akẹkọọ ileewe Kuriga, bii ọọdunrun tawọn janduku agbebọn kan ji gbe wọ’gbo lọsẹ meji sẹyin ti gba ominira lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, awọn agbebọn naa ti tu awọn ọmọ ọhun silẹ lakata wọn.

Gomina ipinlẹ Kaduna, Sẹnetọ Uba Sani, lo kede iroyin ayọ ọhun lasiko to n fi idunnu rẹ han ninu atẹjade kan to buwọ lu, eyi to fi lede lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii.

Ninu atẹjade naa, o ni: “Lorukọ Ọlọrun Allah, Ọba Oloore ati alaanu ju lọ, inu mi dun lati kede pe wọn ti tu awọn ogowẹẹrẹ akẹkọọ ileewe Kuriga silẹ o.

“Ọpẹ wa pataki lọ sọdọ Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, fun ilakaka rẹ lati pese aabo fun awọn ọmọ Naijiria, to si ri i daju pe ko si eyikeyii lara awọn akẹkọọ wọnyi ti wọn ṣe leṣe lakata awọn ajinigbe naa. Ni gbogbo asiko tawọn ọmọ yii fi wa nigbekun, leralera ni emi ati Aarẹ n sọrọ lori aago, o kẹdun pẹlu wa, o rẹ wa lẹkun, o si ṣiṣẹ kara lati ri i pe awọn ọmọ naa ri idande gba lai fara pa.

“Ẹ jẹ ki n tun dupẹ lọwọ Oludamọran pataki si Aarẹ lori eto aabo, Mallam Nuhu Ribadu, fun apẹẹrẹ aṣaaju rere to fi lelẹ. Ọpọ oru lemi ati Ribadu fi sọrọ, ta a n dabaa oniruuru ọna ati ọgbọn-inu ta a le lo lati doola ẹmi awọn ọmọde wọnyi, a dupẹ pe aṣeyọri naa tẹ wa lọwọ.”

Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Kaduna tun dupẹ lọwọ ileeṣẹ ologun ilẹ wa, fun isapa wọn lati rẹyin awọn janduku agbebọn ti wọn n huwa laabi ati ijinigbe kaakiri orileede yii, bẹẹ lo lu gbogbo ọmọ Naijiria lọgọ ẹnu fun adura ati idaniyan wọn latigba ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Ṣaaju, lori ikanni ayelujara rẹ, lo ti gbe fọto ti oun ati Aarẹ Bọla Tinubu ya lasiko abẹwo kan to ṣe si Aarẹ lowurọ ọjọ Satide naa si. O ni Ọga agba ileeṣẹ ologun ilẹ wa, Chief of Defense Staff, Jẹnẹra Christopher Musa, tẹle oun lọ sipade ọhun, tawọn si sọrọ mọran-in mọran-in lojuna bawọn akẹkọọ yii yoo ṣe ri itusilẹ gba.

Tẹ o ba gbagbe, owurọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, lawọn ajinigbe ti wọn dihamọra ya bo ileewe ijọba LEA Primary and Secondary School, to wa lagbegbe Kuriga, nipinlẹ Kaduna. Lasiko tawọn ọmọ ọhun to sori ila laaarọ gẹgẹ bii iṣe wọn, ni wọn ya bo wọn, wọn si ji akẹkọọ ọọdunrun din mẹtala (287) gbe pẹlu ọkada ti wọn gbe wa. Eyi to dagba ju ninu awọn ọmọ ọhun ko ju ọmọọdun mejila lọ.

Amọ ṣa, awọn kan lara awọn akẹkọọ naa raaye sa lọ mọ wọn lọwọ ninu igbo lọjọ keji.

Ṣa, ileeṣẹ ologun ilẹ wa ni aropọ akẹkọọ tawọn ri gba pada lọjọ Satide yii jẹ mẹtadinlogoje (137), mọkanlelọgọta lawọn ọmọdekunrin, nigba tawọn ọmọdebinrin jẹ mẹrindinlọgọrin (76). Mejọ Jẹnera Edward Buba to jẹ Alakooso eto iroyin fun ileeṣẹ ologun ilẹ wa sọ pe agbegbe ipinlẹ Zamfara, lawọn ti ri awọn ogowẹẹrẹ ọhun gba pada, o ni pẹlu iranlọwọ awọn ẹṣọ alaabo mi-in, awọn ọdẹ adugbo ati awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Kaduna lawọn fi ṣaṣeyọri yii, bo tilẹ jẹ pe ko sọrọ pato boya awọn agbebọn naa gbowo itusilẹ, ati iye towo naa le jẹ.

Edward ni awọn ti fa awọn ọmọ naa le ijọba ipinlẹ Kaduna lọwọ, ọgọọrọ awọn obi ati alagbatọ si ni wọn ti n tu jade pẹlu idunnu lati gba ọmọ wọn pada, tori iku ti iba pa ni, to ba ṣi ni ni fila, ọpẹ nla ni.

Leave a Reply