Ta a ba fẹ ki owo Naira gbera si i, eyi lohun tawọn ọmọ Naijiria gbọdọ ṣe-Tinubu

Monisọla Saka

Lojuna ati le buyi kun owo Naira lẹgbẹẹ dọla, Aarẹ Tinubu ti gbe igbesẹ lati ṣeto biliọnu marundinlọgọrin Naira fawọn ileeṣẹ olokoowo nilẹ Naijiria, bẹẹ lo rọ awọn eeyan lati maa ra awọn nnkan ti wọn n ṣe lorilẹ-ede yii, dipo tilẹ okeere.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni Ajuri Ngelale, ti i ṣe oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin sọrọ naa fawọn oniroyin to wa nile ijọba, l’Abuja.

O ni Aarẹ Tinubu n ke si gbogbo ọmọ Naijiria lati gbaruku ti eto yii, nipa rira awọn nnkan ti wọn ba ṣe lorilẹ-ede wa, lati le buyi kun owo Naira, ti adinku yoo si ba iṣẹ ati oṣi lorilẹ-ede wa.

O ni bi owo Naira ṣe ti n gbera pada ta ko dọla yii waye latari akitiyan ti wọn n ṣe lati maa ṣe ayẹwo oko-owo agbaye ni Naijiria.

Tinubu ni ayipada rere ti n foju han, agaga pẹlu bi awọn ileeṣẹ tọrọ kan ṣe n gbe igbesẹ lati ro owo Naira lagbara. Ajuri ni erongba ijọba oun ni lati ri i daju pe awọn ileeṣẹ ti wọn n gba awọn eeyan siṣẹ lọpọ yanturu ni awọn yoo kọkọ mu tiwọn gbọ lori eto tijọba fẹẹ ṣe yii.

Eto yii lo ni o ṣokunfa bi Aarẹ ṣe buwọ lu biliọnu marundinlọgọrin Naira (N75billion), ti wọn fẹẹ pin fun awọn ileeṣẹ olokoowo nla nla marundinlọgọrin kaakiri awọn ipinlẹ lorilẹ-ede yii.

Awọn ileeṣẹ ti wọn gba ọmọ Naijiria to le ni ẹgbẹrun kan siṣẹ nileeṣẹ wọn ni wọn ni eyi to pọ ju nibẹ yoo kan, gẹgẹ bo ṣe wa ninu atẹjade ọhun.

O fi kun un pe bi owo Naira ṣe n lagbara si i yii yoo maa tẹsiwaju, ati pe

erongba ijọba ni lati ri i pe awọn ileeṣẹ nla nla yii ko da awọn oṣiṣẹ wọn silẹ, bi ko ṣe ki wọn tun gba awọn oṣiṣẹ si i.

Ngelale ni Aarẹ n ṣiṣẹ lori bi wọn yoo ṣe ṣafikun awọn oṣiṣẹ ati owo-oṣu to kere ju lọ lorilẹ-ede Naijiria.

Ninu atẹjade naa lo ti ni, “O da mi loju pe gbogbo ọmọ Naijiria lapapọ ti ri ayipada nla to waye lẹnu ọjọ mẹta yii lori ọrọ owo Naira si owo dọla ilẹ Amẹrika.

Ọna to daju pe gbogbo wa fẹẹ dori kọ naa niyi. O si ṣe ni laaanu pe ki i ṣe akoko ta a le sinmi tabi patẹwọ niyi.

“Akoko ta a gbọdọ mura si akitiyan wa, ka si tẹpa mọṣẹ gidi gan-an ni, nitori eyi si ni Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ṣe buwọ lu oniruuru eto ironilagbara to le mu ki owo Naira maa ta kan-n-gbọn pẹlu awọn owo orilẹ-ede agbaye yooku.

“Akọkọ ni pe, Aarẹ Tinubu fẹẹ ba awọn eeyan wa sọrọ, pe ko i ti i si igba kankan ninu itan orilẹ-ede yii tawọn eeyan ti maa n panu-pọ lori ati maa ra awọn ọja ti wọn n ṣe nilẹ wa kaakiri oniruuru ileeṣẹ.

A gbọdọ ni in lọkan pe ta a ba fẹ ki owo Naira gbera si i, ta a fẹ buyi kun owo wa, afi ki a fọwọsowọpọ pẹlu eto yii, gẹgẹ bi Aarẹ ṣe ti gba a lero.

Gbogbo Naira ati kọbọ ta a ba n pa ni a fẹ ko wuyi, nibi yii nikan kọ, ati lawọn ilẹ mi-in ni”.

O ni gbogbo akitiyan ti Aarẹ ti ṣe pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ileeṣẹ ijọba mi-in, to fi mọ banki apapọ lati koju awọn òwò ori ayelujara kan (crypto currency), lo n so eeso rere bayii.

Ngelale ni Aarẹ Tinubu wa n rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ Naijiria, lati maa ra awọn nnkan to jẹ ti ilẹ wa, ati pe akoko ati gbe owo Naira larugẹ ta a wa yii ko ni i tẹti, ti gbogbo rẹ yoo fi ṣẹnuure.

Leave a Reply