Nitori ẹgbẹ ti ko bofin mu to da silẹ, wọn ti foju olori ẹgbẹ Miyetti Allah bale-ẹjọ o

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Ọgbẹni Inyang Ekwo, tile-ẹjọ giga kan niluu Abuja, ni wọn wọ olori ẹgbẹ Fulani ti wọn n pe ni Miyetti Allah, Ọgbẹni Bello Bodejo lọ, ẹsun tijọba Naijiria fi kan an ni pe o da ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Kungiya Zaman Lafiya, tijọba apapọ orileede yii ko fọwọ si silẹ, ati pe ẹgbẹ ọhun jẹ ẹgbẹ kan to le fa laṣiigbo saarin ilu pẹlu igbesẹ wọn.

ALAROYE gbọ pe ọfiisi adajọ agba nilẹ wa lo gbẹjọ ọhun lọ sile-ejọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ti wọn si fẹsun iwa ọdaran ati dida ẹgbẹ alakatakiti to lodi sofin orileede Nigeria silẹ.

Gbogbo ẹsun tawọn olupẹjọ fi kan an pata ni Bodejo sọ pe oun ko jẹbi rẹ pẹlu alaye.

Lasiko igbẹjọ naa ni Agbefọba, Mohammed Abubakar rọ adajọ pe ki wọn kede ọjọ ti igbẹjọ naa yoo waye. O ni awọn ni ẹlẹrii meji lati jẹjọ ta ko ọkunrin naa, bakan naa ni awọn le pe ju bẹẹ lọ bi ile-ẹjọ ba fẹ si i.

Ṣugbọn ninu ọrọ tiẹ, agbẹjọro olujẹjọ, Mohammed Sheriff , sọ ni tiẹ pe ara onibaara oun ko ya, bẹẹ ni wọn ko si fun aọn agbẹjọro rẹ lanfaani lati ri i.

Ninu idajọ, Onidaajọ  Ekwo, sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii.

O ni kawọn ẹṣọ alaabo abẹnu ti wọn n pe ni ’Defence Intelligence Agency’ DIA fi sahaamọ wọn digba ti igbẹjọ maa too waye lori ọrọ rẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii aago mẹrin ku ogun iṣẹju ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni awọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa pẹlu awọn ṣọja ya bo olu ile ẹgbẹ naa to wa oju ọna marosẹ Abuja si Keffi, ni Tundun-Wada, nipinlẹ Nasarawa, ti wọn si gbe ọkunrin naa lọ.

Ẹsun ti wọn tori ẹ mu un nigba naa ni pe o da ẹgbẹ fijilante kan to pe ni Normad Vigilante Group silẹ, eyi to ni yoo maa ṣọ awọn Fulani darandaran ati maaluu wọn. Awọn ọtẹlẹmuyẹ atileeṣẹ ọlọpaa ni ọkunrin naa ko fi igbesẹ yii lọ awọn, bẹẹ ni ko si gba aṣẹ ko too ṣe bẹẹ. Ati pe, ohun to ṣe yii lodi sofin ilẹ wa, wọn ni idasilẹ ẹgbẹ yii le da wahala nla silẹ lorileede yii.

Leave a Reply