Ko gba ko dija: Ibrahim fọbẹ gun akẹkọọ ẹgbẹ ẹ to fẹẹ maa yan lọrẹẹ nitori tiyẹn ko gba fun un

Adewale Adeoye

Ko gba ko dija ni wọn maa n sọ, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ fun akẹkọọ Fasiti Maiduguri kan, Ọgbẹni Saleem Ibrahim, to fọbẹ gun akẹkọọ obinrin ẹlẹgbe rẹ, Omidan Hauwa Abatcha Ngala, ẹni ọdun mọkanlelogun, yannayanna nitori tiyẹn ko gba fun un lati maa yan an lọrẹẹ  ninu ọgba ileewe ọhun.

ALAROYE gbọ pe ẹka ẹkọ ti wọn n kọ nipa itọju alaisan, ‘College Of Nursing Science’ ni akẹkọọ obinrin ọhun wa ni fasiti ọhun ko too di pe Saleem gun un lọbẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

Ṣa o ọwọ awọn agbofinro agbegbe naa tẹ Saleem nibi to sa pamọ si lẹyin to huwa buruku naa tan.

Ọkan lara awọn akẹkọọ ileewe ọhun sọ pe o ti pẹ ti Saleem ti n yọ Huawa lẹnu pe oun fẹẹ maa fẹ ẹ, ṣugbọn tiyẹn ko gba fun un. Gbogbo bi ọmkunrin naa ṣe n daamu akẹkọo yii pe dandan ni ko fẹ oun ni ko gba fun un. Ṣugbọn nigba to di ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, Saleem lọọ ka ọmọbinrin naa mọle to n gbe pẹlu olugbongbo lọwọ, o lu u bajẹ, o si fọ ọ lori pẹtẹpẹtẹ lojọ naa. Lẹyin to hu iwa laabi naa tan lo sa lọ.

Awọn tọrọ naa ṣoju wọn ni wọn gbe Hauwa lọ sileewosan ijọba agbegbe naa fun itọju, lẹyin eyi ni wọn lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti. Loju-ẹsẹ ni wọn ti lọọ fọwọ ofin mu Saleem nibi to wa, wọn fa a le ọlọpaa lọwọ pe ki wọn ba a ṣẹjọ fohun to ṣe yii, ṣugbọn ko ju ọjọ kẹta lẹyin ti wọn ju u sahaamọ  tan ti Akọwe agba fun ijọba ipinlẹ naa, Ọnarebu Bukar Tijjani, fi lọọ gba beeli rẹ lọdọ awọn ọlọpaa agbegbe naa.

Iṣelẹ ọhun lo mu inu bi awọn akẹkọọ ileewe yii ti wọn fi sọrọ odi sawọn alaṣẹ pe iru iwa yii ku diẹ kaato.

Leave a Reply