O ti waa doju ẹ! Awọn agbebọn ya bo awọn ara ọja, wọn pa eeyan bii ogun

Adewale Adeoye

Olori ilu kan, atawọn araalu bii ogun, lawọn agbebọn to ya wọ’nu ọja iṣẹnbaye kan to wa lagbegbe Madaka, nipinlẹ Niger, ti pa danu bayii.

ALAROYE gbọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni wọn de sinu ọja naa to nijọba ibilẹ Rafi ọhun, ti wọn si pa olori ilu naa atawọn ọlọja bii ogun danu loju-ẹsẹ. ALAROYE gbọ pe lasiko tawọn araalu naa n ṣe ka-ra-ka-ta ninu ọja maa lọwọ, ti inu ọja ọhun si kun fọfọ ni wọn ṣiṣẹ buruku naa. Lojiji ni wọn yọ si awọn eeyan ọhun, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn soke gbaugbau. Niṣe ni ọrọ di bo o lọ o yago, nigba tawọn ara ọja naa gburoo ibọn lojiji, ti onikaluku si n gbiyanju lati sa sala fun ẹmi rẹ.

Lasiko naa ni wọn yinbọn pa eeyan bii ogun, ti ọpọ si fara pa. Wọn ti gbe awọn to fara kaasa ninu ijamba naa lọ sileewosan Ibrahim Babangida Specialist Hospita (IBB Specialist Hospital), to wa niluu Minna, bayii.

Yatọ sawọn to pade iku ojiji lọjọ naa, aimọye awọn obinrin atawọn ọmọde ni awọn oniṣẹ ibi ọhun ji gbe sa lọ. Bẹẹ ni wọn tun kina bọ awọn ṣọọbu atawọn mọto tawọn araalu gbe wa sinu ọja naa.

Olori ilu naa, Alhaji Isah Bawale, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ ọhun waye, ṣugbọn awọn agbebọn ọhun ko ti i pe lati sọ ohun ti wọn fẹẹ gba ko too di pe wọn maa tu gbogbo awọn ti wọn ji gbe silẹ.

O rọ ijọba orileede yii atawọn ọlọpaa ipinlẹ naa pe ki wọn dide iranlọwọ sawọn olugbe agbegbe Shiroro, Munya ati Rafi, ki awọn agbebọn ọhun yee waa kogun ja wọn mọ.

 

Leave a Reply