Oloro tilu Oro, AbdulRafiu Ọlaniyi Ajiboye Oyelaran, ti waja

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, ti ba awọn eeyan ilu Oro, nijọba Ìfẹ́lódùn,  kẹdun iku Olóró tilu Òró, Ọba AbdulRafiu Ọlaniyi Ajiboye Oyelaran 1.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni kabiyesi waja.

Atẹjade ti Akọwe iroyin lọfiisi gomina, Rafiu Ajakaye, gbe sita laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, lo ti ni iroyin ibanujẹ gbaa niku ọba naa jẹ fun ijọba ataaralu. Abdulrahman tun ba gbogbo mọlẹbi ati igbimọ lọbalọba nijọba ibilẹ Ìfẹ́lódùn kẹdun. O ni kabiyesi ti kopa ribiribi ninu idagbasoke ilu Òró, o mu ki irẹpọ wa laarin araalu, eyi lo si mu itẹsiwaju ba ilu naa.

Gomina gbadura ki Ọlọrun tẹ ọba alaye naa safẹfẹ rere, ko si tu ẹbi ati araalu ninu.

 

Leave a Reply