Eyi lohun ti Gumi sọ lori ọkunrin ti wọn mu pe o n ṣatilẹyin fawọn afẹmiṣofo

Monisọla Saka

Aafaa nla to filu Kaduna ṣebugbe, to si gbajumọ lori ọrọ awọn ajinigbe ati Boko Haram nni, Sheik Ahmad Gumi, ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ileeṣẹ eto aabo to n tọpinpin ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu, Nigerian Financial Intelligence Unit (NFIU), nitori bi wọn ṣe kede Tukur Mamu, gẹgẹ bii agbatẹru awọn ajinigbe.

Mamu, ti i ṣe oludasilẹ iwe iroyin Desert Herald newspaper, to si ti wa latimọle latinu oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022, ni Gumi sọ pe ajọ NFIU ko laṣẹ lati kede ẹ bii ẹni to n kun awọn apanilẹkunjaye ẹda yii lọwọ.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ogunjọ, oṣu Kẹta yii, ni ajọ NFIU lẹ orukọ Mamu pẹlu awọn mẹjọ kan, atawọn mẹfa mi-in ti wọn maa n ṣẹ owo Naijiria si tilẹ okeere (Bureau de change), gẹgẹ bii awọn to n gbe owo silẹ fawọn agbesunmọmi to n domi alaafia ilu ru.

Ninu ọrọ ti Gumi sọ lo ti ni ile-ẹjọ nikan ni agbara wa ni ikawọ wọn lati kede Mamu pe o jẹbi.

O ni ko yẹ ki wọn fẹnu lasan ṣedajọ ọkunrin naa nita gbangba, lai jẹ pe kootu ṣe bẹẹ.

“Ta lẹni to lẹtọọ lati kede eeyan bii agbatẹru ajinigbe? Ṣe ile-ẹjọ ni abi ileeṣẹ eto aabo? Ileeṣẹ eto aabo ko ni aṣẹ kankan lati kede ẹnikẹni gẹgẹ bii ẹni to n ṣatilẹyin fawọn adaluru.

Ẹjọ ọhun ti wa niwaju ile-ẹjọ, ki lo waa de to jẹ inu iwe iroyin ni wọn ti n fẹnu kan an mọ agbelebuu? Niwọn igba ti ẹjọ kan ba ti wa ni kootu, ẹ maa fun ile-ẹjọ laaye lati dajọ ni.

Nigba ti akọroyin Daily Trust beere ajọṣepọ to wa laarin oun atawọn agbesunmọmi, Gumi ni, “Gbajumọ ni mi. Ọpọlọpọ eeyan lo maa n waa ba mi. Atawọn eeyan gidi, atawọn ẹni ibi. Gẹgẹ bii oniwaasi, mi o le le ẹnikẹni danu, ko si bi ẹni naa ti le jẹ eeyan buruku loju araye to.

Tẹ ẹ ba beere, agaga lọwọ awọn pasitọ, awọn adigunjale maa n waa jẹwọ ẹṣẹ niwaju wọn, ṣugbọn ti wọn ko tun ni i tori ẹ fa wọn lọ siwaju awọn alaṣẹ”.

Gumi ni oun mọ pe gbogbo wahala ti Mamu ko si yii ko sẹyin aigbọra-ẹni-ye to wa laarin oun atawọn igbimọ ti wọn gbe dide lati gba awọn ti wọn ji gbe silẹ.

“Ohun ti mo mọ nipa Mamu ati bi wọn ṣe fi panpẹ ọba gbe e ni nitori ede aiyede to waye laarin oun ati igbimọ to yẹ ko ṣiṣẹ lori itusilẹ awọn eeyan kan ti wọn ji gbe. Amọ niwọn igba ti ọrọ naa ti wa nile-ẹjọ, a nigbagbọ pe wọn yoo da a lare.

“Nnkan ta a ti n fẹ tẹlẹ naa ni pe ki wọn gbe e lọ sile-ẹjọ, dipo ki wọn maa la ẹsun oriṣiiriṣii bọ eeyan lọrun.

Ki wọn mu ẹri wọn wa, ti Mamu ba si jẹbi, ko jiya to ba tọ si i. Ṣugbọn ohun temi mọ lọwọ bayii ni pe ki wọn jẹ ka a duro de idajọ kootu”.

Gumi sọrọ siwaju si i pe iwa igbesunmọmi gan-an ni bi wọn ṣe fi panpẹ ofin gbe Mamu, ti wọn si n foju ẹ rare. O ni lai wo ti pe odidi baale ile ni, wọn gbe e lọ sile-ẹjọ, wọn fi i si atimọle, bẹẹ ni wọn tun n yẹyẹ ẹ. Gbogbo idojuti ati ifiniṣẹsin yii ni Gumi ni ko lorukọ meji ju iwa agbesunmọmi lọ.

O ni bii igba tawọn ajinigbe ba lọ sile eeyan lọọ ji i gbe, bẹẹ ni fifi panpẹ ofin gbe ni lọna ti ko bofin mu naa ṣe jẹ iwa igbesunmọmi.

Leave a Reply