Awọn eleyii naa jira wọn gbe, inu igbo kan ni wọn lọọ sa si

Monisọla Saka

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Adegoke Fayọade, ti gboṣuba kare fawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn ṣiṣẹ takuntakun lati mu awọn mẹrin kan ti wọn jira wọn gbe pamọ, ti wọn si n beere fun miliọnu marun-un Naira.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni SP Benjamin Hundeyin, ti i ṣe alukooro ọlọpaa ipinlẹ Eko fọrọ naa lede.

Awọn mẹrẹẹrin, ti mẹta ninu wọn jẹ obinrin, ati ọkunrin kan, tọwọ tẹ yii ni Margret Itodo, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25), Agnes Ogbe, ẹni ọdun mẹtalelogun (23), Esther Anyanwu, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24), ati ọkunrin kan ṣoṣo to wa laarin wọn, Anthony Chinakwe, toun naa jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun (24).

Gẹgẹ bi Hundeyin ṣe sọ, Agnes lawọn mẹta yooku yii pawọ-pọ fọgbọn gbe pamọ lati le fi gbowo. Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta yii, ni Agnes, ti i ṣe ọmọ bibi ilu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, rinrin-ajo lati Akurẹ wa si Eko, Eko to wa yii naa ni wọn ti parọ pe o ti ko sọwọ awọn ajinigbe.

Niṣe ni wọn fi fidio kan ranṣẹ sawọn mọlẹbi Agnes, niluu Akurẹ. Ninu fidio ọhun ni wọn ti de e lọwọ ati ẹsẹ, wọn fi aṣọ di i lẹnu, bẹẹ lohun funra ẹ n kerora ni ayika ti wọn kan ẹjẹ too too si ko le baa jọ ibuba awọn ajinigbe.

Miliọnu marun-un Naira (5m), ni awọn ayederu ajinigbe yii beere fun lati le yọnda Agnes.

O ni gbara ti wọn fọrọ yii to agbofinro leti lawọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹsẹ bọ ọ.

Ninu ile kan ti Agnes, obinrin mi-in ti wọn dibọn bii pe oun naa wa nigbekun awọn, atawọn meji yii n gbe, ti wọn si ti n ṣe faaji, lawọn ọlọpaa ka wọn mọ.

“Bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ ẹni to mu aba ijinigbe ọhun wa ninu awọn afurasi yii, ninu iwadii ta a ṣe lo ti han pe ojulowo aṣojuloge (Make up artist), ni Margaret Itodo n ṣe, oun ni wọn si gbe iṣẹ naa fun lati jẹ ki gbogbo agbegbe naa jọ ti awọn ajinigbe tootọ. Awọn mẹrẹẹrin ti n ka boroboro lori ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ naa, laipẹ la o si foju wọn bale-ẹjọ ti iwadii ba ti pari”.

Gẹgẹ bi ọrọ ijira-ẹni-gbe ṣe n fojoojumọ gbilẹ si i, kọmiṣanna ọlọpaa Eko waa ke pe awọn olugbe Eko lati maa kiyesara, ki wọn si fẹjọ ohunkohun to ba mu ifura dani to awọn ọlọpaa tabi ẹṣọ alaabo to ba wa nitosi wọn leti.

 

Leave a Reply