Awọn ẹlẹsin ibilẹ, aafaa nla atawọn agba wolii pade nibi eto adura ọjọ kẹjọ Olubadan to waja

 Ọlawale Ajao, Ibadan

Bo ba ṣe pe bi ẹsin eeyan ṣe pọ niye to l’Ọlọrun yoo wo lati ṣedajọ ọmọ ẹda eeyan lode ọrun, ko si ohun to le ka Ọlalekan Balogun lọwọ ko lati ri alujanna tabi ọrun rere wọ, nitori bi gbogbo awọn aṣaaju ẹsin Musulumi, Kirisitẹni atawọn olori ẹlẹsin Abalaye ṣe jokoo papọ lati bẹ Ọlọrun fun oku ọba naa lode ọrun to.

Eyi ko ṣẹyin bo ṣe jẹ pe awọn adari ẹsin mẹtẹẹta ni wọn jọ kopa nibi eto adura ọjọ kẹjọ ipapoda Ọba Balogun, eyi to waye ni gbọngan Mapo, niluu Ibadan, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

Fun awọn ti ko ba mọ,  Musulumi l’Ọba Lekan Balogun, ṣugbọn Kirisitẹni ni meji ninu awọn iyawo mẹta to ni, Olori Yinka Balogun ati Olori Funmilayọ Balogun, nigba ti ọkan yooku, Olori Khalifat Balogun, to jẹ aya afẹgbẹyin rẹ jẹ Musulumi. Bi Ọba Balogun si ṣe sun mọ awọn mejeeji naa lo n ba awọn ẹlẹsin ibilẹ ṣe.

Ta o ba gbaGbe, awọn Ogboni ṣetutu, bẹẹ ni wọn wure si oku ọba naa lara ko too di pe awọn musulumi sin in lẹyin ti wọn kirun si i lara tan.

Lara awọn eekan ilu to kopa nibi ijokoo adura ọjọ kẹjọ ipapoda ọba naa ni gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Sẹnetọ Rashidi Ladọja, to tun jẹ Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan lọwọlọwọ;  Aarẹ Musulumi ilẹ Yorubaland, Alhaji Daud Akinọla; Sẹnetọ Kọla Balogun, ti i ṣe aburo Olubadan to waja; ati Ọnarebu Ṣẹgun Ọlaiwọla, ti i ṣe Kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati eto oye jijẹ ni ipinlẹ Ọyọ.

Awọn yooku ni Aarẹ ẹgbẹ igbimọ awọn agba ọmọ ibilẹ Ibadan, Amofin Niyi Ajewọle; Iyalọja ipinlẹ Ọyọ, Alhaja Saratu Konibajẹ; Baba Isalẹ Musulumi ilẹ Ibadan, Alhaji Nureni Akanbi; Alhaja Iswat Ameringun, ti i ṣe Iyalọja ilẹ Ibadan, ati bẹẹ, bẹẹ lọ.

Ninu iwaasu rẹ nibi akanṣe adura ọhun, Ọjọgbọn Kamil Ọlọṣọ, sọ pe o ṣe pataki fun gbogbo eeyan lati maa kopa nibi eto isinku ẹni to ba ku, nitori iyẹn ni yoo jẹ ki wọn maa ranti iku nigba gbogbo, ki wọn si maa huwa rere lojoojumọ pẹlu ijọsin fun Ọlọrun.

Aṣaaju ẹsin Kirisitẹni kan, Pasitọ Olusọji Adediji, naa kin ọrọ ọjọgbọn yii lẹyin, o ni iku lopin irinajo ẹda lorilẹ aye. Bẹẹ lo ṣapejuwe Ọba Balogun gẹgẹ bii ẹni to gbe igbesi aye to nitumọ ṣaaju, ati lasiko to wa lori itẹ gẹgẹ bii Olubadan ilẹ Ibadan.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, l’Ọba Balogun waja sileewosan ijọba apapọ, University College Hospital (UCH), n’Ibadan, ti wọn si sinku rẹ si agboole wọn ni Aliwo, n’Ibadan, lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii kan naa.

Leave a Reply