Gbogbo ileewe pamari ati sẹkọndiri gbọdọ ni fẹnsi ati kamẹra aṣofofo nipinlẹ Ogun -Kọmiṣanna ọlọpaa

Faith Adebọla

Ọkan-o-jọkan amọran ati aba ti waye lati ro eto aabo lagbara dan-in-dan-in lawọn ileewe alakọọbẹrẹ, iyẹn pamari, atawọn ileewe girama, sẹkọndiri, jake-jado ipinlẹ Ogun, eyi ti awọn alakooso ileewe wọnyi gbọdọ gbe yẹwo, ki wọn si ṣamulo rẹ lẹyẹ-o-sọka.

Eyi waye nibi apero akanṣe kan ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, labẹ idari Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Abiọdun Mustapha Alamutu, ṣagbekalẹ rẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

Apero ọhun, eyi ti awọn Oludamọran pataki si gomina ipinlẹ Ogun lori eto aabo, awọn alakooso ileewe girama ati aṣoju ẹgbẹ awọn olori ileewe alakọọbẹrẹ pesẹ si, titi kan awọn aṣoju ajọ eleto aabo bii so-safe, awọn fijilante, awọn ẹgbẹ ọdẹ, awọn olori ilu ati ileto, waye ni gbọngan apero POWA, to wa lolu-ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, l’Eleweẹran, niluu Abẹokuta.

Ninu ọrọ rẹ, Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, Abiọdun Alamutu, ni ilana oju lalakan fi n sọri, ati pe igi ganganran ma gun mi loju, okeere laa ti i lọ ọ. Eyi ni ọga ọlọpaa naa ni o mu ki awọn pepade apero naa latari bi iṣẹlẹ ijinigbe, ṣiṣe akọlu sawọn ileewe, jiji awọn akẹkọọ atawọn ogowẹẹrẹ gbe, ati eto aabo ti ọga ọlọpaa patapata, IG Kayọde Ẹgbẹtokun, la kalẹ lasiko yii, wa lara ohun to mu ki apero naa ṣe pataki.

Alamutu ni nibi tọrọ de bayii, o yẹ, o si pọn dandan, ki gbogbo awọn ileewe pamari ati sẹkọndiri, ibaa jẹ tijọba tabi ti aladaani, lọọ mọ fẹnsi yika ileewe wọn, ki wọn si ṣeto kamẹra atanilolobo (CCTV) sawọn ayika wọn.

Kọmiṣanna ni ko ṣee ṣe fun ileeṣẹ ọlọpaa lati pese agbofinro sawọn ileewe kọọkan, amọ nipasẹ ajọṣe to danmọran laarin awọn alakooso ileewe, ati araalu to yi wọn ka, pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa, o ṣee ṣe ki afẹfẹ ijinigbe to n ja ranyin ma ṣe de sakaani wọn.

Kọmiṣanna tun dabaa pe ki ileewe kọọkan maa ṣakọsilẹ to peye nipa awọn alejo to n wọle, tabi jade ninu ọgba, ki wọn gbe igbimọ eto aabo kalẹ nileewe kọọkan, ki wọn si tete maa ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo ni gbara ti wọn ba ti ri irinsi tabi akiyesi to mu ifura lọwọ.

Lẹyin ọrọ rẹ lawọn olukopa to wa nikalẹ sọrọ lori awọn ipenija ti wọn n koju, bii aisi awọn ọlọdẹ to dangajia, aisi awọn nnkan eelo aabo bii ọkọ ati owo nla ti ipese aabo n beere fun.

Leave a Reply