Nibi tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti n ṣepade l’Oṣogbo lawọn ọlọpaa ti ko wọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹta ni ọwọ ọlọpaa ti tẹ lagbegbe Oṣogbo bayii.

Gẹgẹ bi ẹnikan to n gbe ni Alékúwodò, ṣe ṣalaye, o ni ọjọ ti pẹ ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti n yọ awọn eeyan agbegbe ọhun lẹnu.

O ni laipẹ yii ni wọn kora jọ lati ṣepade, asiko naa lawọn kan fi to awọn ọlọpaa leti, inu ipade ọhun ni wọn wa ti awọn ọlọpaa, Ọṣun Anticultism Squad fi debẹ.

A gbọ pe bi wọn ṣe foju gan-an-ni awọn ọlọpaa ni wọn juba ehoro, ṣugbọn ọwọ pada tẹ mẹta lara wọn.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun akọroyin wa, o ni ni nnkan bii aago mejila ọsan kọja diẹ lọwọ tẹ wọn ni Alekuwodo, niluu Oṣogbo.

Ọpalọla ṣalaye pe awọn araalu ni wọn ta awọn ọlọpaa lolobo pe awọn eeyan naa n da adugbo laamu. O ni awọn mẹta ti ọwọ tẹ ti jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye Confraternity lawọn.

Leave a Reply