Ọwọ ti tẹ Sodiq l’Oṣogbo, ọkada mẹta ni wọn ka mọ ọn lọwọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan bayii ni tolohun, eyi lo ṣẹ mọ ọmọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Sodiq, toọwọ tẹ laipẹ yii pe o maa n gba ọkada ti awọn ẹni ẹlẹni fi oogun oju wọn ra, ti yoo si lọọ ta a danu lowo pọọku.

Ki i ṣe Sodiq nikan lo maa n ṣiṣẹ laabi yii, a gbọ pe wọn pọ ti wọn maa n ja ọkada gba lọwọ awọn ọlọkada lagbegbe garaaji Ileṣa, niluu Oṣogbo.

Ṣugbọn lọjọ ti ọwọ palaba wọn yoo segi ninu ọsẹ ti a wa yii, awọn ẹka to n gbogun ti ṣiṣe ẹgbẹ okunkun, awọn ọlọdẹ ati awọn aṣọgbo (forest security service) ni wọn jọ n dọdẹ awọn oniṣẹ ibi kaakiri ilu Oṣogbo.

Bi wọn ṣe de garaaji Ileṣa, ni wọn ba Sodiq atawọn ẹgbẹ rẹ nibi to mu ifura dani, Sodiq nikan si lọwọ tẹ nitori kia lawọn to ku sa wọgbo lọ.

Ẹnikan tiṣẹlẹ ọhun ṣojuu rẹ ṣalaye fun akọroyin wa pe ọkada oriṣii mẹta ni wọn ri gba lọwọ Sodiq lọjọ naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe iṣẹ ti bẹrẹ ni pẹrẹu lati mu awọn alaabaṣiṣẹpọ Sodiq ti wọn sa lọ, ki gbogbo wọn le foju bale-ẹjọ lati le jẹ ẹkọ fun awọn to ba tun n hu iru iwa bẹẹ.

Leave a Reply