Abẹẹ rawọn ọmọleewe yii, niṣe ni wọn jira wọn gbe, ti wọn si n beere owo itusilẹ lọwọ obi wọn

Monisọla Saka

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ awọn akẹkọọ meji kan, Ayọdele Balogun, ẹni ọdun mọkanlelogun (21), to wa nipele ẹkọ keji ni Fasiti awọn olukọ to wa ni Ijanikin, nipinlẹ Eko, iyẹn, Lagos State University of Education, ati Dennis Okunomo, ẹni ọdun mọkanlelogun, toun wa nileewe giga National Institute of Information Technology (NIIT). Irọ banta banta lawọn ọmọ naa gbe kalẹ pe wọn ji awọn gbe.

Gẹgẹ bi Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, ṣe sọ, Okunomo lo mu aba naa wa, nitori ati le re ọwọ jọ fun Balogun, tawọn obi rẹ ko ri jajẹ.

Lọjọ keji, oṣu Keji, ọdun yii, ni wọn ni Balogun ṣadeede kuro nile, to si fi foonu rẹ fi atẹjiṣẹ ṣọwọ si baba ẹ pe wọn ti ji oun gbe, ati pe ẹgbẹrun lọna ogun dọla ($20,000) ni o gbọdọ mu wa lati gba oun silẹ. Bẹẹ lo duro lori pe owo-ori ayelujara ti wọn n pe ni Bitcoin, ni awọn to ji oun gbe ni ki baba oun fi sanwo, lẹyin naa ni wọn fi asunwọn bitcoin ti yoo sanwo si ranṣẹ si i.

Baba Balogun to jẹ awakọ nileeṣẹ kan sọ fawọn alaṣẹ ileeṣẹ naa lati ran oun lọwọ lojuna ati ko owo naa jọ, ṣugbọn ti wọn ko da a lohun, dipo eyi, awọn ọlọpaa ni wọn ni ko lọọ fọrọ naa to leti ki wọn le bẹrẹ itọpinpin.

“Ninu ile baba Okunomo, nibi ti iyẹn ti da yara ni, ni Balogun lọ lati duro ti ọrẹ ẹ, ṣugbọn nigba ti wọn ko ri owo itusilẹ ti wọn n reti, wọn wọnu igbo lọ lati ya fọto Balogun nihooho ninu igbo to sun si lati le fi ṣẹru ba baba ẹ. Lẹyin naa ni wọn fi fọto ọhun ranṣẹ si Baba Balogun, pe awọn yoo ṣe e leṣe ti wọn ko ba gbowo naa wa ni kia.

“Okunomo ni baba Balogun tun pe lati beere boya o mọ’bi ti ọmọ oun wa, amọ to parọ pe oun ko mọ bo ṣe rin.

Nigba tawọn ọmọ mejeeji ri i pe nnkan kan ko tibi gbogbo ọgbọn tawọn da yọ, ni Okunomo naa dibọn bii pe wọn ji oun gbe, pẹlu erongba pe baba oun maa sanwo kia, oun yoo si ko o le ọrẹ oun, Balogun lọwọ.

“Wọn da a bii ọgbọn bi ẹni pe ajinigbe kan naa to ji Balogun lo ji ọrẹ ẹ, Okunomo, wahala ba tun kun wahala fawọn ẹbi mejeeji, wọn bẹrẹ si i sa koloba koloba kiri.

Bo ṣe di pe wọn tun fi fọto ihooho Okunomo ranṣẹ si baba tiẹ naa niyẹn, wọn ṣafikun owo itusilẹ lati ẹgbẹrun lọna ogun dọla si ọgọrin ẹgbẹrun dọla, lati gba awọn mejeeji silẹ.

“Nigba ti wọn ko gbọ nnkan kan lati ọdọ ẹbi mejeeji, ni wọn tun sun owo naa soke si ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un dọla. Nitori pe Okunomo naa dibọn pe wọn ji oun gbe yii, o ṣoro fun wọn lati duro ni otẹẹli baba ẹ, eyi lo ṣe jẹ pe inu igbo kan to wa nitosi ni wọn fara pamọ si.

“Ọjọ marun-un gbako ni wọn lo ninu igbo naa, nigba to di ọjọ keji ti wọn ko wọnu igbo yii, wọn yọ lọ si ileeṣẹ ti baba Balogun ti n ṣiṣẹ lati ya fọto ayika ibẹ, fọto yii ni wọn lo lati fi halẹ pe awọn mọ’bi ti baba naa ti n ṣiṣẹ, ati pe awọn n bọ waa ji oun naa gbe.

“Ihalẹ yii ba baba naa lẹru pupọ, o si fi to ileeṣẹ leti. Nitori eyi, wọn kede ọrọ naa fun gbogbo awọn oṣiṣẹ, wọn gba awọn ẹṣọ alaabo kun awọn to wa nilẹ, wọn si bẹrẹ si i ṣiwọ iṣẹ ju igba ti kaluku maa n lọ sile tẹlẹ lọ.

“Nigba ti wọn ko ri nnkan kan, lawọn ọmọ mejeeji yii dari pada si otẹẹli baba Okunomo, alaye ti wọn ṣe ni pe awọn jajabọ lọwọ awọn ajinigbe naa ni. Nibẹ naa ni wọn ti fi panpẹ ofin gbe wọn.

Lasiko ifọrọwanilẹnuwo lawọn ọlọpaa ri i pe irọ ni wọn fi ọrọ ijinigbe wọn pa, lojuna ati le fi gbowo lọwọ awọn obi wọn”.

Hundeyin ni iwadii ti bẹrẹ, ati pe ni kete to ba ti pari lawọn yoo wọ awọn mejeeji lọ siwaju adajọ.

Leave a Reply