L’Ondo, adajọ ni ki Wisdom sare lọọ lo ọdun mẹfa lẹwọn pẹlu iṣẹ aṣekara

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kootu Majisireeti to wa niluu Ondo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, ti ni ki ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Alloy Wisdom, lọọ f’asọ penpe roko ọba fun odidi ọdun mẹfa gbako fun jijẹbi ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.

Agbefọba, Benard Ọlagbayi, ka awọn ẹsun ti wọn fi kan ọdaraqn naa si i leti nigba to f’oju b’ale-ẹjọ naa fungba akọkọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ogunjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii. O ni ko din lawọn oniṣowo mẹjọ ti Wisdom ja lole nigboro Ondo ati agbegbe rẹ laarin ọdun 2020 si oṣu Kẹfa, ọdun 2022.

Ọlagbayi ni ọdaran ọhun ni irinsẹ kan to n lo lati fọ awọn ṣọọbu to n ja lole, eyi ti yoo fun un lanfaani lati raaye wọle lati ko gbogbo awọn nnkan ti wọn n ta nibẹ. Apapọ iye awọn owo ẹru ẹlẹru to ti ji ko kọwọ palaba rẹ too ṣegi lo ni yoo ti to bii miliọnu meje Naira.

Agbefọba ni awọn ẹsun mejeeji ti oun ka si ọdaran naa lẹsẹ lo ta ko abala okoo le lẹẹẹdẹgbẹta din mẹrin (516) ati irinwo le mẹtala ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006, to si ni ijiya to rọ mọ ọn.

Lọgan ni olujẹjọ ti gba pe oun jẹbi awọn ẹsun naa, ẹbẹ llo si bẹrẹ si i bẹ pe ki adajọ foriji oun, bẹẹ lo ṣeleri pe oun ko tun jẹ dan iru iwa palapala bẹe wo mọ laye oun.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Charity Adeyanju ni ohun to wa nilẹ yii ti kọja ẹbẹ, o waa paṣẹ pe ki ọdaran ọhun sare lọọ fẹwọn ọdun mẹfa jura lai ni owo itanran ninu.

Leave a Reply