Ọwọ tẹ awọn eleyii, oriṣiiriṣii ayederu ọti ni wọn n ṣe l’Agege

Adewale Adeoye

Mẹrin lara awọn ọdaran kan to jẹ pe wọn ti jingiri ninu ṣiṣe ayederu ọti waini atawọn oriṣiiriṣii ọti mi-in ni Agege, nipinlẹ Eko, lọwọ awọn ọlọpaa agbegbe Isọkoko, ti tẹ bayii, wọn si ti n ran awọn agbofinro lọwọ ninu iwadii wọn lati le ri awọn ẹlẹgbẹ wọn ti wọn ti sa lọ mu.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun akọroyin wa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe awọn owuyẹ kan ti wọn mọ nipa iṣẹ laabi tawọn ọdaran ọhun n ṣe laarin ilu ni wọn waa fiṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa agbegbe Isọkoko, ni Agege, leti, tawọn yẹn si lọọ fọwọ ofin mu wọn. Mẹrin ninu awọn oniṣẹẹbi ọhun ti wọn ba lẹnu iṣẹ  naa ni wọn ti fi ọwọ ofin mu, ti wọn si ti ju wọn sahaamọ awọn ọlọpaa loju-ẹsẹ

Oniruuru ayederu ọti waini atawọn oriṣiiriṣii ọti mi-in ni wọn ba lakata wọn.

Alukoro ni awọn maa too foju gbogbo wọn bale-ẹjọ ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn tori rẹ mu wọn.

 

Leave a Reply