Ere agbere: Iyaale ile binu para ẹ lẹyin t’ọkọ ka ale mọ ọn lori

Adewale Adeoye

O da bii pe itiju aa ti i gbọ lo mu ki iyaale ile kan, Abilekọ Mai Aisha, to jẹ ọmọ orileede Zimbabwe, ṣugbọn toun pẹlu ọkọ rẹ, Ọgbẹni Baba Aisha, n gbe lorileede South Africa, binu para ẹ, lẹyin ti ọkọ rẹ ka ale mọ ọn lori tiyẹn n ṣe yinkun yinkun pẹlu rẹ. Majele inu agolo kan ni wọn ni oloogbe naa gbe jẹ lẹyin ti aṣiri ifẹ ikọkọ  to ni pẹlu ọrẹ ọkọ rẹ tu sita gbangba laipẹ yii.

ALAROYE gbọ pe o ṣe diẹ ti iyaale ile ọhun ti n yan Ọgbẹni Madzibaba to jẹ  ọrẹ kori-kosun ọkọ rẹ, ti wọn tun jọ n ṣiṣẹ pọ lọrẹẹ, ṣugbọn ti ko han sẹnikankan. Laipẹ yii ni Ọgbẹni Baba Aisha ti i ṣe ọkọ oloogbe naa pada wa sile lati ibi iṣẹ, to si ba iyawo rẹ labẹ ọrẹ rẹ Ọgbẹni Madzibaba ninu ile ti wọn jọ n gbe, ti wọn n ṣe ‘kinni’ funra wọn lọwọ. Loju-ẹsẹ ni Baba Aisha ti figbe bọnu, tawọn araadugbo si sare waa wo ohun to n ṣẹlẹ lọjọ naa. Itiju nla gba a lọrọ ọhun jẹ fun iyaale ile ọhun, lo ba sare faṣọ boju.

Lọjọ keji iṣẹlẹ ọhun ni wọn ni obinrin naa gbe majele jẹ, nitori itiju iṣẹlẹ ọhun pọ ju fun un.

Ninu ọrọ Ọgbẹni Baba Aisha ti i ṣe ọkọ oloogbe naa, o sọ pe iyalenu nla gbaa lọrọ iku iyawo oun jẹ foun, nitori pe lẹyin toun ka iwa palapala naa mọ ọn lọwọ tan loun pẹlu rẹ jọọ sọrọ laarin ara awọn, tawọn si jọ fẹnu ko pe, o gbọdọ pada siluu Kumba Kwavo, lorileede Zimbabwe, nibi tawọn ti wa, ṣugbọn nitori pe itiju nla gbaa lọrọ ọhun jẹ fun un lo ṣe kuku ro o pin, to si gbe majele jẹ k’oun too de lati ibiiṣẹ lọjọ keji ti iṣẹlẹ ọhun waye.

Baba Aisha ni ‘Mi o mọ pe iyawo mi le gbe iru igbesẹ yii rara, loootọ ni mo ka a pẹlu ale rẹ, Ọgbẹni Madzibaba, ti i ṣe ọrẹ kori-kosun mi nibi iṣẹ, ṣugbọn mi o binu si i, a jọ sọrọ ọhun pe ko pada sabule wa ta a ti wa, mo tiẹ ti ra tikẹẹti mọto to maa wọ lọ siluu wa fun un, ṣugbọn ṣe lo gbe majele jẹ ki n too de, o si kọ lẹta sẹgbẹẹ rẹ lati sọ idi to ṣe hu iru iwa radarada bẹẹ fun mi.

 

Leave a Reply