Abiru ki leleyii, awọn agbebọn kọ lu mọto akero, wọn ji ero inu ẹ gbe lọ

Adewale Adeoye

Odidi mọto ero kan to jẹ ti ipinlẹ Katsina, iyẹn, ‘Katsina State Transport Authority’ (KTSTA) lawọn agbebọn kan fipa da duro, ti wọn si ko mẹjọ ninu awọn ero to wa ninu ọkọ ọhun wọgbo lọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mejila ọsan Ọjọbọ ọhun ni wọn lọọ dena de dẹrẹba ọkọ akero ọhun lojuna marosẹ to n gba kọja lọ lagbegbe Burdugau si Yargoje, lojuna marosẹ Kankara, nijọba ibilẹ Kankara, nipinlẹ Katsina.

Yatọ si awọn ero mẹjọ ti wọn ji gbe yii, wọn tun ṣe awọn ero kọọkan leṣe gidigidi, tawọn yẹn si n gba itọju lọwọ nileewsọna ijọba agegbe naa.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ijọba nileeṣẹ naa ṣalaye pe lati ilu Funtua, ni ọkọ akero ọhun ti nọmba rẹ jẹ 14B -300-KT, ti gbera, to si n lọ siluu Katsina, ko too di pe awọn oniṣẹ ibi ọhun da a lọna, ti wọn si ji awọn ero inu mọto ọhun gbe sa lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, ASP Abubarkar Sadiq Aliyu, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe mẹjọ lara awọn ero to wa ninu mọto akero ọhun ni wọn ji gbe lọ.

Alukoro ni awọn ti n ṣiṣẹ takuntakun labẹnu lati gba awọn ero mẹjọ ọhun pada lọwọ awọn oniṣẹ ibi ọhun.

 

Leave a Reply