Lẹyin ọsẹ kan ti Olubadan waja, Makinde ṣabẹwo sawọn ẹbi ọba naa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ọsẹ kan  ti Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Mohood Ọlalekan Balogun waja, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti ṣabẹwo si idile oloogbe naa nile ẹ to wa laduugbo Alarere, n’Ibadan.

Nigba to n sọrọ lasiko abẹwo ọhun lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun (21), oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, Gomina Makinde, fidi ipinnu ijọba rẹ mulẹ lati ṣayẹyẹ inawo alarinrin fun ipapoda ọba to waja naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nigba ti mo gbọ pe baba wa ni UCH, mo pe awọn alakooso ilewosan yẹn pe gbogbo nnkan ti wọn ba le mu sa loogun ni ki wọn ṣe lati jẹ ki baba lalaafia, o si da mi loju pe itọju to daa ju lọ ni wọn ṣe fun Kabiesi. Ṣugbọn aisan la ri wo, ẹnikan ko ri tọlọjọ ṣe.

“Ibaṣepọ to wa laarin emi pẹlu baba kọja ọrọ oṣelu nikan, ṣugbọn ọpọ eeyan le ma mọ bi emi pẹlu Kabiesi ṣe sun mọra to.

‘Asiko ti baba wa lori itẹ, wọn mu ayipada rere ba ọrọ oye jijẹ nilẹ Ibadan. A ko ni lati maa ṣọfọ nitori ipapoda Kabiesi, niṣe lo yẹ ka maa dupẹ, nitori ohun rere gbogbo ti wọn gbele aye ṣe.

“Ijọba wa ti ṣeto owo ta a fi maa ṣẹyẹ ikẹyin fun Kabiesi to waja, a maa gbe owo naa jade nigba ti asiko ba to.”

Miliọnu marundinlọgọta Naira (N55m) l’ALAROYE gbọ pe Gomina Makinde ti fọwọ si gẹgẹ bii owo ti ijọba rẹ yoo na lori ayẹyẹ oku ọba naa lẹyin ti aawẹ Ramadan to n lọ lọwọ yii ba pari.

Sẹnetọ Kọla Balogun, to jẹ aburo Olubadan to dara pọ mọ awọn baba nla ẹ yii, pẹlu awọn Ayaba Ọba Balogun mẹtẹẹta, iyẹn, Olori Yinka Balogun, Olori Funmilayọ Balogun ati Olori Khalifat Balogun, ni wọn gba gomina lalejo lasiko abẹwo naa.

Leave a Reply